Iku Mavrodi: Àwọn olùdókòwò MMM ń fi apá jánú

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Sergei Mavrodi lo da ìlànà sogúndogójì MMM sílẹ̀.

''Bi anfaani ba wa, ma tun se MMM lẹ́kan si''

Esi ti Olatunde Oladimeji fọ re nigba ti ikọ́ BBC Yoruba baa sọrọ lori iroyin to gbale kan pe olùdásílẹ̀ ìlànà sogúndogójì, MMM, Sergei Mavrod ti salaisi.

Tunde wa lara aìmọye mílíọ̀nù eniyan lagbaye to padanu owo wọn sọwọ Sergei Mavrodi laarin ọdun 1990 si 2017, sugbọn ko banuje lori iroyin iku Mavrodi.

O ni èrè ti oun jẹ lara MMM ki se die.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIriwisi Tunde,oludokowo lori MMM

Sugbọn fun arabirin Lydia, ọrọ ko ri bee.

O ni bi oun se gbọ́ iroyin iku Mavrodi, n se ni ọkan oun baje nitori owo oun ba ilana sogúndogójì MMM lọ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIriwisi Lydia,oludokowo lori MMM

Sogúndogójì ko le tan

Akọsẹmọsẹ kan nipa eto idokowo, Rotimi Obende ni pẹlu bi nnkan ti se ri, ko daju wi pẹ awọn ọmọ orileede Naijiria yoo dẹyin lẹyin ilana sogúndogójì.

Image copyright Rotimi Obende
Àkọlé àwòrán Ilu okere nikan ni ofin to munodoko wa lati dẹkun idokowo sogúndogójì

Nigba ti o'n ba BBC Yoruba sọrọ, o ni ainitẹlọrun lo maa n sun ọpọ eeyan debi ilana sogundogoji yii.

'Ojukokoro lo wa nidi rẹ. Lopin igba ti awọn oludari ilana naa ba ti n se ileri ere tabua fun awọn eniyan, ọpọ ko ni sin lẹyin re.''

''Aisi ofin to le dẹkun idokowo sogundogoji bayi naa tun se okunfa bi awọn eniyan ti se n wa ọna alumọkọrọyi lati ri owo ifa.''

O wa gba awọn ọmọ orilẹẹde Naijiria nimọran pe ki won,'' sọra daada ki wọn to fi owo wọn sinu ilana ti wọn ko mọ eni to wa ni idi re''