Ilé isẹ́ ọlọ́pàá n wa Dino Melaye

Dínò Mèláye Image copyright Dino Melaye/Facebook
Àkọlé àwòrán Dino Melaye ti fun ile isẹ ọlọ́pàá ni wákàtí mejidinlaadọta lati wa awọn ọ̀daràn to s'sálọ.

Ilé isẹ́ ọlọpaa ti kede ni Ọjọ́rùú pe awọn n wá asòfin to n soju ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Kogi, Dino Melaye ati Muhammed Audu to jẹ́ ọmọ Gomina ọun tẹ́lẹ̀ ri, Abubakar Audu.

Èsùn ti wọn fi kan Melaye ati Audu ni pe wọn fún Ilé isẹ́ ọlọpaa ni ẹ̀rí ti kii se òdodo, lori ẹjọ́ kan ti Melaye pè pé awọn kan fẹ́ gba ẹ̀mí oun lọ́dún to kọja.

Ninu àtẹ̀jáde kan ti Ilé isẹ́ ọlọpaa fi síta lati ọwọ́ kọmisọna ọlọpaa ni ipinlẹ Kogi ni wọ́n ti kéde ọ̀rọ̀ ọ̀ún.

Saájú ni Melaye ti sọ pe oun jọ̀wọ́ ara ọ fun Ilé isẹ́ ọlọpaa fun ìwádìí, sugbọn ti o ni afi to ba jẹ́ pe ìwádìí ọ̀ún yoo waye ni ilu Abuja, nitori pe, o ni ẹ̀mí oun wa ninu ewu ti oun ba wá si Kogi.

Bakan naa, a gb pe, giwa ile isẹ ọlọ́pàá Ibrahim Idris ti yọ Kọmísọ́nà ọlọ́pàá ni ipinlẹ Kogi Ali Janga ati awọn ọ̀gá ọlọ́pàá miiran lóyè, lori bi afurasi meji ti wọn fi si àhámọ́ lori ọ̀rọ̀ Melaye se fi papa bora.

Related Topics