PDP fèsì sí orúkọ àwọn asèbàjẹ́ ti ìjọba Nàíjiríà gbe jade

Aworan Goodluck Jonathan lọdun 2015 Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Alaga ẹgbẹ Oselu PDP, Uche Secondus, Alukoro ẹgbẹ Oselu PDP tẹlẹri, Olisa Metuh wa lara oruko awon asebajẹ

Ẹgbẹ́ òsèlú PDP lòrílẹ́èdè Nàíjiríà ti bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn orúkọ ti ìjọba orilẹede Naijiria gbe jade gẹ́gẹ́ bi awọn to lu owo ilu ni ponpo labẹ ijọba PDP fun ọdun mẹrinlelogun.

Minisita fọrọ Iroyin, Lai Muhammed to fi orukọ awọn eniyan naa lede ninu atẹjade fun awọn oniroyin sọrọ ni ilu Eko, sọ wi pe awọn to lu owo ilu ni ponpo naa jẹ gbajugbaja ninu ẹgbẹ òṣelu PDP.

Lara awọn ti Lai Muhammed darukọ ni Alaga ẹgbẹ Oselu PDP, Uche Secondus, Alukoro ẹgbẹ Oselu PDP tẹlẹri, Olisa Metuh, Alaga ile isẹ DAAR Communications, Raymond Dokpesi, Dudafa Waripamo-Owei ati Robert Azibaola.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lórí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀, Twitter, àwọn ẹgbẹ oselu PDP sọwipe kosi otitọ kankan ninu orukọ ti ẹgbẹ oselu APC gbe jade nitoriwipe ile ẹjọ kankan ko tii da wọn lẹbi lilu owo ilu ni ponpo.