Kò si ẹ̀ri fún ìbò ọmọ kékèké ni Kano — Ganduje

Abdullahi Ganduje Image copyright KANO STATE DG MEDIA

Gómìnà ìpinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje, ní kò si ọ̀titọ́ ninú ọ̀rọ̀ pe àwọn ọmọ kèkèké dìbò ninú ìbò ìjọbá ìbilẹ̀ tí wọ́n dì ní ìpinlẹ̀ náà lasìkò tí àwọn èèyàn sì ń rẹtí èsì ìwadi ìgbìmọ tí ajọ tó ń ṣe ètò ìdìbò Nàìjíríà (INEC) yan latí ṣe ìwadi lórí àwọn fídíò tó fi hàn pe àwọn ọmọde kopa ninú ìbò ìjọbá ìbilẹ̀ ni Kano.

Lẹyín ìgbà tí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí fi ìbànújẹ́ hàn lórí fídíò náà ni alága àjọ INEC, Ọ̀mọ̀wé Mahmoud Yakubu yan ìgbìmọ̀ ti Abubakar Nahuce lewajú ko ṣe ìwádi lórí iwe ìf'orúkọ́ silẹ̀ tí wọ́n lò ni Kano.

Bótílẹ̀ jẹ́ pé ìgbìmọ̀ náà nawọ́ ẹ̀sì ìwádi rẹ̀ fun INEC latí oṣù tó kọ́já, àwọn èèyàn ko tíì mọ ẹ̀sì náà.

Sùgbọn nigbà tó ń ba àwọn akọ̀rọ̀yìn sọ̀rọ̀ ni l'Abuja, Ganduje sọ wipe fídíò náà kíì ṣe ògidì.