Awọn ọmọ Chibok- 'Mẹ́ẹ̀dógún lókù tó wà láàyè'

Awọn afẹ̀hunnu han. Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Loni lo pé ọdún mẹ́rin geere ti wọn ko ọ̀rìnlérúgba o din mẹ́rin ọmọbìrin ni ileewe girama to wà ni Chibok

Akọ̀ròyìn kan to ní àjọse pẹlu ikọ̀ Boko Haram ti sọ pe, mẹ́ẹ̀dógún péré ló kù tó wà láàyè ninu ọmọ méjìléláàádọ́fà to si wà láhàámọ́ awọn Boko Haram ninu awọn ti wọ́n jí gbé ni ilu Chibok.

Ọgbẹ́ni Ahmad Salkida sọ pe, oun gbìyànjú lati dúnàá dúrà pẹlu ikọ̀ ọun lori bi wọn yoo se da awọn ọmọ wọ̀yí silẹ̀, sugbọn ti gbogbo ìgbìyànjú oun já sí pàbó.

Ọgbẹ́ni Salkida tún sọ pe ìsèjọba ààrẹ àná Goodluck Jonathan rọ oun lati dúnàá dúrà lori dídá awọn ọmọ ọun sílẹ̀ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ meji ti wọ́n ko wọn lọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ninu ìsèjọba aarẹ Jonathan ni wọn ti ji awọn ọmọ ọ̀ún ko lọdun 2014

O ni oun wá gbìyànjú lati lati sètò síse pàsípààrọ̀ awọn ọmọ ọ̀ún pẹlu awọn afurasí ọmọ ikọ̀ Boko Haram ti ìjọba mú nigba naa, sùgbọ́n tó jẹ́ pe, èèemarùún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni eléyìí já si pàbó latari bí ìjọba Goodluck Jonathan se fi ọ̀rọ̀ naa falẹ̀.

Ìgbàgbọ́ wà pé, ìkọ̀lù awọn ọmọ ogun ilẹ̀ Naijiria ló sekú pa ọ̀pọ̀ ninu awọn ọmọ náà.

Ọgbẹ́ni Salkida kò sàfihàn orukọ awọn ọmọ mẹ́ẹ̀dógún tó sọ pe wọ́n sẹ́kù yii, ó sọ pe ojúse ìjọba ni èyí.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ǹjẹ́ wọn yoo dá awọn ọmọ Chibok tókù sílẹ̀?

Agbẹnusọ ijọba kan ti sọ fun ile isẹ́ BBC pe, awọn si wa lori dídúnàá dúrà pẹ̀lú ikọ̀ Boko Haram lori bi wọn yoo se tú awọn ọmọbirin méjìléláàádọ́fà ọun to wà ninu àhámọ́ wọn sílẹ̀, ati pé, awọn ò ní káàárẹ̀ lori ìgbìyànjú awọn.

O tún fi kúun pe, awọn ò ni ìdí kankan lati gbàgbọ́ pe lara awọn ọmọ náà ti jáláìsí.