Premier League: Salah, Mane fi àmì tuntun lélẹ̀

Salah fẹ gba bọọlu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Salah àti Mane ti di èèkàn nínú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Liverpool

Ìlúmọ̀ọ́ká agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀èdè Egypt nì, Mohammed Salah ti di agbábọ́ọ̀lù ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tó gbá góòlù tó jẹ góòlù tó pọ̀jù ní sáà ìdíje bọ́ọ̀lù kan ní líìgì Premiership.

Goolu to gba wọle fun ikọ rẹ, Liverpool ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Bournemouth lọjọ abamẹta lo gbee lọ si tente oke pẹlu ọgbọn goolu.

Salah àti Mane ti sọ ara wọn di ògúnnágbòǹgbò nínú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Liverpool.

Bi a ko ba si ni gbagbe, o ṣi ku ifẹsẹwọnsẹ mẹrin ki saa bọọlu liigi ti ọdun yii to pari.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Liverpool bori ifẹsẹwọnsẹ àwọn àti Bournemouth pẹlu ami ayo mẹta si odo

Ki o to di asiko yii, gbajugbaja agbabọọlu orilẹede Ivory Coast ni, Didier Drogba lo gba goolu wole ju pẹlu goolu mọkandinlọgbọ to gba wọle ni saa liigi ọdun 2009/2010 fun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea

Kaakiri gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ti Salah ti gba fun Liverpool ni saa yii, ogoji goolu lo ti wa ni ikawọ rẹ

Bakanaa ni Sadio Mane, agbabọọlu orilẹede Senegal pẹlu to n gba bọọlu jẹun ni Liverpool gba goolu tirẹ wọle pẹlu.

Mane ni agabọọlu ọmọ orilẹede Senegal ti goolu rẹ pọju lọ bayii ni idije premiership pẹlu goolu mẹrinlelogoji to ti gba wọle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: