Manchester City gba ife ẹ̀yẹ EPL

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKi ni ero ọgbẹni Pep Guardiola?

Egbẹ́ agbabọọlu Manchester City ti gba ife English Premier League, lẹyin ti Manchester United pàdánù ninu ìdíje pẹlu ẹgbẹ́ agbabọọlu West Brom pẹlu ami ayò kan si òdo.

Ìsẹ́jú kejìléláàdọ́rin ni Jay Rodriguez gba bọ́ọ́lù ọ̀ún wọnú àwọ̀n fun West Brom lẹyin ti gbogbo ìgbìyànjú Manchester United lati gba bọọlu wọnú àwọ̀n já sí pàbó.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gbogbo ìgbìyànjú Manchester United ni kò so èso

Ìyàlẹ́nu lo jẹ́ fun gbogbo ònwòran ni Old Trafford nigba ti Man United kùnà lati dá góòlù West Brom pada.

Lọ́sẹ̀ to kọjá ni City jìyà lọ́wọ́ United nígbà ti wọ́n nà wọ́n ni àmì ayò mẹ́ta si méjì. Sugbọn lọ́gán ni City padà s'ípò ni ọjọ́ àbámẹ́ta nigba ti wọn na Tottenham pẹ̀lú àmà ayò mẹ́ta si ẹyọkan, ni pápá ìseré Wembly.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìgbà àkọ́kọ́ rèé ti Pep Guardiola yoo gba EPL fun Manchester City lẹ́yìn to gba ife ẹ̀yẹ Carabao

Ni ọjọ́ Ìsẹ́gun to kọjá ni City kógbá kúrò ninu idije Champions League lẹ́yín ti Liverpool fàgbà han wọ́n ni ìpele to kángun si èyí tó tẹ̀lẹ́ àsekágbá.