Asòfin Nàíjíríà; Báwo ni iléesẹ́ òfúrufú se ná 462 mílíọ́nu dọ́là?

Aworan Ile Igbimo Asofin Kwara Image copyright TWITTER/ALI AHMAD
Àkọlé àwòrán Sẹnatọ kan ni wọn yọ owo iyebiye naa kuro ninu apo ifowopamọ ijọba apapọ ni Osu to kọja

Ile igbimọ asofin agba lorilẹede Naijiria ti pe Gomina Banki Apapọ Naijiria (CBN), Godwin Emiefele , Minisita feto inawo, Kemi Adeosun ati Minisita fọrọ eto aabo, Mansur Dan-Ali lori bii wọn se na ejilelọgọtalelẹrinwo milliọnu owo okeere (462 million dollars) lati fi ra ọkọ ofurufu mẹfa fun ile isẹ ọmọogun ofurufu Naijiria.

Sẹnatọ kan ni ile igbimọ asofin agba sọwipe wọn yọ owo iyebiye naa kuro ninu apo ifowopamọ ijọba apapọ ni Osu to kọja lai gba asẹ lati ile igbimọ asofin.

Sẹnatọ kan ni wọn yọ owo iyebiye naa kuro ninu apo ifowopamọ ijọba apapọ ni Osu to kọja

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Sẹnatọ kan ni wọn yọ owo iyebiye naa kuro ninu apo ifowopamọ ijọba apapọ ni Osu to kọja

Ijọba orilẹede Naijiria n koju eeto abo to mẹhẹ kaakiri awọn ilu to wa lorilẹede naa, ti wọn si ni lo ohun elo ija lati mu ki eto abo o muna doko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbon, ileri Aarẹ Muhammadu Buhari lati koju iwa ibajẹ lawujo yoo mu ki awọn ọmọ orilẹede Naijira o beere bii ijọba se naa ejilelọgọtalelẹrinwo milliọnu owo okeere lati fi ra ọkọ ofurufu.