Èkó: Ẹ́ san owó orí lóríi ilé tẹ́ẹ sọ di iléèjọsin

Igbimọ ileeṣẹ ọrọ abẹle nipinlẹ Eko Image copyright LASG
Àkọlé àwòrán Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ní ọgbọ́n àti sá fún owó orí sísan ni áwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ń dá

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti f'ohùn sílẹ̀ pé kò sí ààyè fún sísọ iléègbé di iléèjọsìn mọ́ ní ìpínlẹ̀ náà.

San owó orí bí ó ti yẹ

Kọmíṣọ́nà fọ́rọ̀ abẹ́lé, Abdul Hakeem Abdul Lateef ló sọ èyí nílùú Èkó.Ó ní Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti kẹ́ẹ́fín pé àwọn onílé kan ń sọ ilé wọn di ilé ìjósìn lọ́nà àti sá fún sísan owó orí ilẹ̀ àti ilé níbẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, "fún àwọn tó ń lo ilé wọn fún ilé ìjósìn, mọ́ṣáláṣí tàbí ṣọ́ọ̀ṣì, a ko ni wo ile bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n bi a ti sọ ṣaaju, gbogbo ile ni yoo san owo ori ileegbe ati ilẹ̀.

Ẹ ko gbọdọ̀ sọ pé mọ́ṣáláṣí tàbí sọ́ọ́sì wa nisalẹ ile yin

Bi àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba bá de, ẹ ko gbọdọ̀ sọ pé mọ́ṣáláṣí tàbí sọ́ọ́sì wa nisalẹ."O ni gbogbo ile ti won ba kọ̀wé rẹ̀ fún ìjọba gégébí iléègbé ni yóò san owó orí yìí.