Àdó olóró Iran: Trump ati Macron fẹ́ s’àdéhùn tuntun

Aarẹ Donald Trump ati Aarẹ Macron Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn adari naa wipe adehun tuntun naa yoo koju aibale okan to n sẹlẹ ni Middile East.

Aarẹ Amerika, Donald Trump ati akẹẹgbẹ́ rẹ̀ nilẹ Faranse, Emmanuel Macron, ti ní, awọn yoo se adehun tuntun lori ado oloro asekupani ọlọgọọrọ ti orilẹede Iran n se.

Lẹyin ti awọn adari mejeeji jọ jiroro tán ní orílẹ̀èdè, ni Trump ti ko ni ifẹ si adehun ti awọn orilẹede fọwọsi lọdun 2015 nipa Iran, sọ wipe oun yoo gbiyanju lati se adehun miran to dara ju ti tẹlẹ lọ.

Ninu ọrọ ti rẹ, Macron ni adehun tuntun naa yoo seto nipa ado oloro ọlọgọọrọ ti Iran n gbe kalẹ ati ipa rẹ ni agbegbe Middle East.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ, orilẹede Iran ti kilọ fun ilẹ Amẹrika lati mase gbiyanju da adehun ti wọn se nu, nitori yoo ni ipa ti kii se kekere.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Lọpọ igba ni Iran ti bu ẹnu atẹ lu igbiyanju aarẹ Trump lati se adehun tuntun

Bakan naa, olori orilẹede Germany, Angela Merkel, yoo se abẹwo si ilẹ Amerika ni Ọjọbọ ọsẹ yii, lati jiroro pẹlu Aarẹ Trump, lati mase fagile adehun ti wọn se pẹlu Iran.

Adehun naa faye gba Iran lati dawọ sise ado oloro tuntun duro

Ti a ko ba gbagbe, ọpọ igba ni Aarẹ Donald Trump ti sọ wipe oun ko ni tẹsiwaju pẹlu adehun ti wọn se pẹlu Iran, eleyi ti yoo dopin ni Ọjọ Kejila, Osu Karun, Ọdun 2018.

Adehun ti Iran se pẹlu awọn orilẹede agbaye naa, faye gba Iran lati dawọ sise ado oloro tuntun duro, ti awọn orilẹede naa ba dẹ okun ofin ọrọ aje ti wọn fi de wọn.