Buhari: ọmọ ni Lai Mohammed lóri lẹ́tà Ọbásanjó

Aare Nigeria, Muhammadu Buhari Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ààrẹ ní òun kọ́kọ́ sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ fèsì sí lẹ́tà Obasanjọ

Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣàlàyé lóri èrò rẹ̀ lóríi lẹ́tà Ọbásanjọ́.

O ní Minisita fun Ìroyìn, Lai Mohammed, ni ó pàrọwà sí òun lóríi lẹ́tà tí ààrẹ àná, ìyeń, Olóyè Olusegun Ọbásanjọ́ kọ nínú èyí tí ó sọ àwọn ìdí tí kò yẹ kí òun fi padà sorí àleéfà lẹ́ẹ̀kejì.

Nígbà tí ó n sọ̀rọ̀ ninú àseyẹ kan tí íjọba Ìpínlẹ̀ Bauchi gbé kalẹ̀ láti yẹ́ẹ sí ní Ojọ́bọ, ààrẹ ní òun ti kọ́kọ́ sọ fún àwọn agbẹnusọ òun pé wọn kò gbọ́dọ̀ fèsì, ṣugbọn Mohammed ni ó sọ pé ìjọba gbọ́dọ̀ dá Obasanjo lóhùn.

Buhari tún sọ pé léhìn tí òun lọ́ra láti gbà síi lẹ́nu, Lai Mohammed ní ó yẹ kí a fèsì, ṣùgbón nínú èsì náà, wón kò gbọ́dọ̀ dárúkọ Obasanjo.

Ààrẹ ní, "Nígbà tí Lai Mohammed bẹ̀rẹ̀ sí ní tara nípa lẹ́ta tí wọ́n kọ nípa àwọn àiṣedáadáa wa, mo ní rárá, kí ó máa lọ. Súgbọ́n ó kọ̀ sí mi lẹ́nu. Nígbà tí ó ṣàlàyé tán, mo ri wí pé òótọ́ ni.

Ó ṣe dáadáa ní tòótọ́ nítorí pé gbogbo àwọn tí ó kàn símí lẹ́yin tí wón gbọ́ èsì wa ni wọ́n sọ wí pé Lai Mohammed ṣe dáadáa."

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Obasanjo sọ fún Buhari pé kó gbàgbé sáà kejì

Ẹ ó rántí pé nínú lẹ́tà rẹ̀, Obasanjo tẹ́ pẹpẹ gbogbo àwọn ǹkan tí ó lérò pé ó ṣe kókó tí Buhari kò tíì yanjú rẹ̀.

Ó sì sọ fún Buhari pé kó gbàgbé sáà kejì, lẹ́hìn náà ni ó sọ pé kí àwọn ọ̀dọ́ má dìbò fun ààrẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: