Dan Evans: Ogún osù tó nira jùlọ fún mí láyé

Àwòrán Dan Evans lórí pápá Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ǹ kan míìràn tó tún nira ní pé mí ò le sọ fún ẹbí àti ọ̀rẹ́

Gbajugbaja agbaboolu ẹlẹyin lórí ọ̀dàn, Dan Evans sọ pé ohun búburú gbaa ni lílo oògùn olóró.

Ó ní, òun to banilẹru ni láti kojú, ti àbájáde rẹ bá dé fún elere ìdárayá tàbí ẹnikẹni.Evans sọ fún ikọ ìròyìn BBC pé, nínú ìdíje kan tó wáyé ní Barcelona ni òun ti lo oogun olóró náà tí àgbéyèwò sì fi í hàn ní gbangba.Ó ní èyí fẹẹ bá òun láyé je tán pẹlu igbẹ́sele ọdún mẹ́rin gbáko ṣùgbọ́n tí ẹgbẹ́ ITF sadinku rẹ pé òògùn olóró Cocain kii fún ní lágbára láti ṣiṣẹ àti pé kíi ṣe àsìkò ìdíje loun lo o.Fún ìdí èyí òun kò ṣe ìdíje kankan fún ọdún kan àti oṣù mẹjọ gbáko.