Ikọ̀lù Darandaran: ìwọ́de pẹ̀lẹ́ kùtù wáyé nípìnlẹ̀ mẹ́ta

Àwọn olùwóde Image copyright TITTER/ANTHONY BERNARD
Àkọlé àwòrán Ààrẹ CAN ni ìwọde náà wa fun pipe àkíyèsí ìjọba sí ipaniyan jákèjádò Naijiria

ìwọde òní pẹ̀lẹ́ kùtù ń lọ lọ́wọ́ nípìnlẹ̀ Òndó, Osun àti Èkìtì. Leyin ìkéde adarí àjọ CAN ẹni ọwọ Olasupo Ayokunle lọ́jọ́ru pé kí gbogbo onigbagbọ ṣe ìwọde lágbègbè wọn láti pé àkíyèsí ijoba fún ífòpin sí Ipànìyàn láti ọwọ àwọn darandaran, pàápàá jùlo àwọn Kristẹni tí wọn pá ni Ìpínlẹ̀ Benue.

Alága àjọ CAN ni Ìpínlẹ̀ Òndó, Ẹni ọwọ Ayọ̀ Oladapo tó bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ààrẹ CAN ni ìwọde náà láti pé àkíyèsí ìjọba sí ipaniyan jákèjádò.

Image copyright Toba Adedeji
Àkọlé àwòrán ìwọde náà n waye nípìnlẹ̀ Osun ati Ekiti bakan naa

Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ pé àwọn ìjọ tó kú yóò mú ọjọ́ tó bá wù wọn láti ṣe ìwọde tiwọn, ṣùgbọ́n ìròyìn kan òun lára pé Ọsun àti Èkìtì náà ń ṣe ìwọde tí wọn lọ́wọ́.

''Èkó àti àwọn Ìpínlẹ̀ miran náà yóò sì bẹ̀rẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ títi di ọjọ́ ìsinmi tó ń bọ̀''

Lójú òpó twitter ní ṣe làwọn olùwọ́de ń fi àwọ̀ran ìwọ̀de hàn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: