Dókítà: Kòsí iyatọ láàrin Codein ati DXM

Aworan oògùn ìkọ olómi
Àkọlé àwòrán Ipenija nla ni asilo oògùn ìkọ olómi to ni Codein nínú.

Awọn onimọ ìsegun ni Naijiria ti ni ko si agba ninu ọmọ aja laarin eroja codeine ati Dexromethorpan, ti wọn tun n da pe ni DXM .

Wọn ni oogun to lee se ijanba fun ara ati ọ̀pọ̀lọ̀ ni eroja mejeeji to ba pọ lapọju ninu ara.

Awọn dokita naa fesi yii nigba ti wọn n sọ̀ ero ọkan wọn si bi ijọba se kede pe oun ti gbẹsẹ le kiko eroja codeine wọle ati lilo eroja naa fun oogun ikọ̀.

Wọn ni aja n loso, a lọ fi owo ra ọbọ, bẹẹ ni ọbọ naa ko ni owo meji, ju ko joko lọ, ni ọrọ codein ati DXM, nitori ikahun-ikahun, bii igba kanhun ni eroja mejeeji.

Ọrọ naa ko sẹyin fídíò iwadi ti ile iṣẹ BBC gbé jade lori aburú ti Codein n fa láàrin àwọn ọmọ orílèèdè paapa julọ awọn ọdọ.

Idi si ree ti mínísítà fún ọrọ ìlera lorílèèdè Nàìjíríà fi kéde laipẹ yii pe ijọba ti fòfin dè títà àti rírà oògùn ìkọ olómi to ni Codein nínú.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Dípò eroja codein, wọn ni ki awon apoogun maa lo eroja kàn ti orúkọ rẹ n je Dextromethorpan, taa mọ̀ si DXM.

Àkọlé àwòrán Fidio BBC mu ki ijọba fofin dè títà àti rírà oògùn ìkọ olómi to ni Codein nínú.

Ninu ìfòròwánilénuwò pẹlú àwọn onímọ̀ ìṣẹgun, Dokita Hafeez Olajire ati Dokita Maruf Mustapha, sọ fún BBC Yorùbá pé, kò sí iyatọ láàrin àwọn ogun méjèjì.

''Ọrọ naa dàbí ki a ta ajá nítorí pé ọ n loso, ki a wa fi ọwọ ra obo. Obo sí rèe, bàbá loso loso níí. ''

Codein ati Dextromethorpan, gẹgẹ bí àlàyé ti Dokita Hafeez Olajire ṣe, jẹ ''oògùn tí o n ṣiṣe lati dẹkùn ọwọjá ikọ́ awugbẹ.

Ise kannáà ni won ṣe. Iyatọ die lo kan wà nínú bí wọn ti ṣe má mu kí èèyàn kundun lilo wọn.

''Bí wọn bá ní Dexromethorpan ni yóò rọpo Codein, awọn tó n lo oògùn nilokulo yóò sì padà sí ìdí rè tí wọn kò bá rí Codein mo.

''Bakanna kinni ki awọn to ni ìkọ gbigbẹ ṣe?''

Àkọlé àwòrán Ọrọ naa ko yo omode sile.Koda awọn obirin naa teri si aburu yii

Amukun eru è wọ́

Dokita Maruf Mustapha ni oke ni ìjọba wo, ko wo ilẹ, lati se agbekale ofin tuntun yii nipa ọrọ asilo oògùn to gbòde.

''Bi ìkọ ṣe jẹ owoja àìsàn míi, bẹẹ náà ni asilo oògùn jẹ owoja àìsàn míi, to je aibikita ilana tita oògùn lorílèèdè yìí.''

Image copyright AFP/PIUS UTOMI EKPEI
Àkọlé àwòrán Ọpọ ma n ta oògùn tí Dókítà ko fọwọ si

O ni awọn akoogun ti yan iṣẹ ti kii ṣe tí wọn láàyò. 'Won kò l'ase láti máa se oògùn tàbí tá oògùn tí Dókítà ko ba fọwọ si fún aláìsàn."

Niwọn ìgbà tí isesi bayi ba gbòde, ipenija ilokulo oogùn ko le kase nílé.''

Ọna Abay

Ijọba àpapọ̀ ti fòfin de títà àti rírà tramadol àti oògùn ikọ́ olómi to ni codeine.

Dókítà Mustapha ni, igbésẹ tó dáa ni fún ìgbà díè ṣugbọn lẹyìn rẹ, kò lè dẹkùn lílò oogùn yi lọnà tí kò tọ.

Àkọlé àwòrán O tó mílíọ̀nù mẹta ìgò oògùn ìkọ ti wọn n mú ní Kano ati Jigawa lojumọ.

''oun ti ìjọba ni lati se ni ki wọn fún okùn mó òfin lórí títà àwọn oògùn lorílèèdè Nàìjíríà, pàápàá jùlọ, àwọn oògùn tí o ma n ṣe iṣẹ oríṣiríṣi.''

''Àwọn aláìsàn yóò ma nilo awọn oògùn fún àìsàn kan tàbí òmíràn.

Fun ìdí èyí a gbọdọ ri pe àwọn tó nilo oogùn gangan ni wọn n tá fún.''