Ghana: Ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú NNP fọ́ akọ̀ròyìn létí

Àwọn eeyan to n fapa janu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ́ akòròyìn Ghana ni, àwọn ń ròó lọ́wọ́, bóyá ìlànà òfin ní àwón yóò fi yanjú ọ̀rọ̀ òhún.

Obìnrin ajàfẹ́tọ́ fún ẹgbẹ́ òṣèlú to ń bẹ lóde ní orílẹ̀-èdè Ghana, tí bá ara rẹ̀ nínú wàhálà àìrótẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn akòròyìn, lẹ́yin to gbá ọ̀kan lára wọn létí.Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn to tẹ BBC Yoruba lọ́wọ́ ṣe sọ, arábìnrin òhun ti orúkọ rẹ ń jẹ Hajia Fati, gbá akòròyìn òhun létí nítorí pé ó fẹ́ ya òun ni fótò. Lẹ́yìn náà ni obìnrin náà bá tún gbìyànjú láti ràrò jàre ọ̀rọ̀ náà wípé, akòròyìn òhun jọ onísòwò àlùbọ́sà ni.Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn obìnrin Ìkòròdú: Ọdún orò kò ni wá lára rara

Ó tún ṣàlàyé pé, òun rò pé ọkàn lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú alátakò ni.Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ akòròyìn órílẹ̀-èdè Ghana ni, àwọn ń ròó lọ́wọ́, bóyá ìlànà òfin ní àwón yóò fi yanjú ọ̀rọ̀ òhún.