Ìdìbò abélé: Buhari gbóríyìn fún àwọn akọpa nínú ìdíje

Ààrẹ Muhammadu Buhari Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ààrẹ kí Fayemi ti yóò sojú ẹgbẹ́ òṣèlú APC fún ipò Gómìnà tí yóò wáyé ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kèje

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Muhammadu Buhari tí kí Káyọ̀dé Fáyẹmí tó jáwé borí nínú ìdìbò abẹ́le tó wáyé lánàá ní ìpínẹ̀ Ekiti kú orí ire.

Ààrẹ kí Fayemi ti yóò sojú ẹgbẹ́ òṣèlú APC fún ipò Gómìnà tí yóò wáyé ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kèje ọdún 2018.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nínú onírúúrú ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti orí ẹ̀rọ ayélujára twitter Ààrẹ ní òun kò kí Fayemi nìkan fún jíjáwé olúborí láti ṣoju APC fún ìdìbò to ń bọ̀, òun tún ní ìgbàgbọ́ pé gbogbo awọn iṣẹ́ tó làmìlaaka tó ti ṣe fún ètò ẹ̀kọ́, ìlera àti mímójú tó ìgbáyégbádùn aráàlú yóò wúlò fún láti yege níbi ìdìbò to ń bọ̀.

Buhari gbóríyìn fún gbogbo àwọn olùkópa níbi ìdìbò abẹ́lé náà.

Ó ní pẹ̀lú àwọn olùkópa tó lé ní ọgbọ̀n, tí wọn sì ṣe àṣeyọrí, ààrẹ ní èyí fihàn pé ìṣejọba àwa arawa gbilẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ekiti.

Ó rọ wọn láti fọwasowọ́pọ̀ pẹ̀lú Fayemi ní ìdìbò Gómìnà tó ń bọ̀.

Ààrẹ fí dá gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ oṣelu APC lójú pé òun yóò ṣiṣẹ́ takuntakun láti ríi dájú pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dé èbúté ògo nínú ìdàgbàsókè