Ilé isẹ́ America ní Jerusalem; Ẹ̀mí Palestine 41 bọ́

Awọn ara Isreali joko Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idunnu su bu lu ayọ fun awọn ara Israeli

Orilẹede Amẹrika ti si ile isẹ rẹ tuntun si Jerusalem, eyi jẹ igbese ti àwọn ọmọ ilẹ̀ Palestine ta ko pẹlu ifẹhọnu hàn ọlọgọọrọ.

Iroyin fi lede wi pe, awọn ọtọkulu orilẹede Amẹrika ló péjú sibi ayẹyẹ naa, pẹlu ọmọ Aarẹ Donald Trump. Ivanka ati ọkọ rẹ, Jared Kushner.

Igbesẹ Aare Donald Trump lati gbe ile isẹ Amerika kuro ni Tel Aviv, bi awọn ara Palestine ninu nitori wi pe wọn ni Ila Oorun Jerusalem ni olu ilu wọn ni ọjọ iwaju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin kan ni, o kere tan, ọmọ ilẹ Palestine mọkanlelogoji lo ti ba isẹlẹ naa rin, ti ẹgbẹrun kan mii si fi ara pa lẹba aala ilẹ Israel to wa ni Gaza lọjọ aje.

Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Awọn ara Palestine hun fẹhọnu han lori igbesẹ Aarẹ Donald Trump

Amọ, ilẹ Isreal wi pe Jerusalem ni olu ilu wọn lati igba iwasẹ ti ko si si ẹni to le yii pada.

Ero Aarẹ Trump lati gbe ile isẹ re lọ si Jerusalem ni o fopin si igbesẹ Ilẹ Amẹrika lati ọdun gbọọrọ lati ma dasi aigbọra ẹni ye laarin ilẹ mejeeji.