Wole Soyinka: Pańpẹ́ ọba lọ̀nà àbáyọ sí ìwà ìbàjẹ́

Ọjọgbọn Wọle Soyinka Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán 'Àwọn asèbàjẹ́ gbọ́dọ̀ fi ẹ̀wọ̀n ju 'ra'

Ọjọgbọn ati onkọwe ni, Wọle Soyinka ti sọ wi pe ayafi ti awọn asebajẹ ba bẹrẹ si ni fi ẹwon ju 'ra, ko le e si opin si iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria.

Soyinka sọ eyi ni Abuja nibi ipade ẹlẹẹkẹjọ Ajọ Commonwealth fun awọn adari ile-isẹ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni ilẹ Afirika.

Onkọwe naa nigba to se abẹwo si ile isẹ tuntun awọn ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC sọ wi pe ohun fẹ mọ bi wọn se n setoju awọn asebajẹ to wa ni panpẹ wọn si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIfọrọwanilẹnuwo pẹlu Ọjogbọn Wọle Soyinka

Soyinka ni ojuse ile isẹ to n koju iwa ajẹbanu ni lati gba awọn owo ti awọn asebajẹ ji ko pada lati fi mu ibugboro ba ọrọ ajẹ orilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: