Ọmọge Campus kú ni ọdún kan tí Moji Ọlaiya dará ilẹ̀

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMoji Olaiya: Lẹ́yìn ọdun kan

Bí a bá ń rebi, à dá ni lógún ọdún, bí á bá ràjò, à dá ni lọ́gbọ̀n osú, Moji Ọlaiya ree nínú fídíò òkè yìí, tó lọ, láà dá ìgbà kan.

Òní ló pé ọdún kan gbáko tí gbajúgbajà òṣèré obìnrin, Moji Olaiya re ìwàlẹ̀ àsà.

Síbẹ̀ gbogbo ọmọ Nàìjíríà àti àwọn olólùfẹ Moji Olaiya ṣi ń ṣèrántí akọni to ti lọ náà

Tẹ́ ò bá gbàgbé, Moji Olaiya kú ni ọjọ́rú, ọjọkẹtàdínlógún oṣù karùnún ọdún 2017, lẹ́yìn tí ó bí ọmọ kejì sí orílẹ̀-èdè Canada.

Image copyright Instagram/Moji Olaiya
Àkọlé àwòrán Moji Olaiya pe ọdun kan tó jade laye

Ó jẹ́ ọmọ gbajúgbajà olórin juju High life kan, Victor Ọlaiya.

Moji ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lu Báyọ̀ Okesola lọ́dun 2007, o kopa nínú àwọn ere bii Sade Blade ", "Nkan adun", "Omo iya meta leyii", No Pains No Gain," "Nkan Adun" àti "Agunbaniro" ".

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Image copyright Instagram/MOji Olaiya
Àkọlé àwòrán Moji Olaiya kopa ninu ọpọlọpọ ere ni ede Yoruba ati Geesi nigba aye rẹ

Kín ní àwọn ọ̀rẹ́ ń sọ lẹ́yìn ọdún kan nípa Moji Ọláìyá?

Ọ̀pọ̀ àwọn òsèré Nollywood, tí BBC Yorùbá kàn sí láti sọ̀rọ̀ lórí bí wọn se mọ ipa àlàfo tí ológbèé náà fi si sílẹ̀ lára, ló ń mí ìmí ẹ̀dùn lọ́wọ́ nítorí ikú akọni òsèré-bìnrin mii, Aisha Abimbọla, tóun náà tẹ́rí gbasọ lákòkò tó pé ọdún kan géérégé tí Moji Ọlaiya di ará ilẹ̀, tí wọn kò sì fẹ sọ ohunkohun nítorí ọ̀rọ̀ ti pèsì jẹ.

Àmọ́, àwọn èèyàn díẹ̀ sì rántí ọdún kan tí a kò rí Moji Ọlaiya mọ́ lójú òpó ikansira ẹni wọn lórí ìtàkùn àgbéyé wọn.