Ileesẹ Ọ́lọ́pàá: Kò tọ́ kí ọlọ́pàá yẹ fóónu aráàlú wò láìsẹ̀

Aworan a\wn ọlọpaa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán N jẹ́ o mọ̀ pé ó pọndandan kí o kọ́kọ́ yẹ ọlọ́pàá wò kí o tó yẹ̀ ọ wò.

N jẹ́ o mọ̀ pé ó pọn dandan kí o kọ́kọ́ yẹ ọlọ́pàá wò kí o tó yẹ̀ ọ wò?

Igbákejì Agbẹnusọ fun ilé isẹ́ Ọlọ́pàá, Abayọmi Shogunlẹ fi idanilẹkọ yii sita fawọn aráàlú lórí òpó Twitter nípa àwọn ẹ̀tọ́ tí aráàlú ni lásìkò tí wọ́n bá ń kojú ọlọ́pàá.

Shogunlẹ ni ko bojumu rara fun ọlọpaa kankan lati maa yẹ ẹrọ ibara-ẹni sọrọ araalu wo, lai jẹ pe wọn ti gbọ awawi saaju nipa irufẹ ẹni bẹẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ileesẹ Ọlọpaa Naijiria ti n se idanilkọọ fawọn osisẹ rẹ pe o lodi sofin fun wọn lati maa yẹ foonu araalu wo lai bikita, ti ko ba jẹ pe wọn ti wa fi ẹsun onitọun sun saaju.

Abayọmi sàlàyé pé ó ṣe pàtàkì kí àráàlú gbé ìgbẹ̀sẹ yìí nínú ìrẹ̀lẹ̀

Nigba to n dahun ibeere lori boya Ọlọpaa ti ko wọ asọ lee yẹ ile, moto abi ara araalu wo. Shogunlẹ ni, ti ọlọ́pàá náà kò bá wọ aṣọ, o se pàtàkì kí o mú káàdì ìdánimọ rẹ̀ jáde, ko sì yẹ orúkọ, ipò, ati àgọ́ ọlọ́pàá tí ó ti wá, kí ó to yẹ̀ ọ wò.

N jẹ taa ba wa bi ni, se awọn araalu mọ irufẹ awọn ẹtọ yii bi? Bawo si ni wọn se n mu lo si? Ọpọ awọn to ba wa sọrọ lo ni eyi ko lee rọrun fun awọn ọmọ Naijiria lati se rara.

Ẹ gbọ awọn araalu kan ti BBC Yoruba fọrọ-jomitoro ọrọ pẹlu wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀjọ ọlọ́pàá: kọ́kọ́ sàyẹ̀wò ọlọ́pàá kó tó yẹ̀ ọ́ wò

Awọn alaye ọrọ ọga ọlọpaa Shogunlẹ yii ati iha tawọn araalu kọ sii, lo wa mu ka tọ amofin kan lọ pe kinni ofin sọ nipa awọn ọrọ yii. Se araalu lasẹ tabi lee ni igboya pe ki ọlọpa gbe ara rẹ silẹ, ki oun yẹ wo o abi beere iwe idanimọ ọl pa ko to lee yẹ oun wo, paapa taa ba wo irufẹ ibasepọ to wa laarin araalu ati awọn ọlọpaa lọwọ-lọwọ ba yii.

Amofin Sulaiman Abaya salaye lkunrrẹ lori eleyii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀjọ ọlọ́pàá: kọ́kọ́ sàyẹ̀wò ọlọ́pàá kó tó yẹ̀ ọ́ wò