Congo vs Nigeria; Leopard ti wà ní pẹsẹ́ ní Port Harcourt

Maapu
Àkọlé àwòrán,

Ìgba keje ni yii ti ikọ mejeeji yoo koju ara wọn fun igbaradi ife ẹyẹ agbaye.

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu agba fun ilẹ DR Congo ti de si Naijiria fun ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ pẹlu ikọ Super Eagles.

Lara àwọn ikọ agbabọọlu DR Congo tó ti de si ipinlẹ Rivers fun ifẹsẹwọnsẹ ti yoo waye ni ọjọ Aje ni Cedric Bakambu, Benik Afobe ati Gael Kakuta.

John Mikel Obi ni yóò dari àwọn ti Nàìjíríà.

Ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye ni papa isere Adokiye Amiesimake, ni ipinlẹ naa ni yoo jẹ igba keje ti ikọ mejeeji yoo koju ara wọn fun igbaradi ife ẹyẹ lagbaye.

Àkọlé fídíò,

'Oúnjẹ ibìkan jẹ́ èèwọ̀ ibòmíì ni ọ̀rọ̀ ọmú ńlá'

Lẹyin ifẹsẹwọnse ọjọ Aje naa ni ikọ Super Eagles yoo lo koju ẹgbẹ agbabọọlu England ni ọjọ Keji, Osu to m bọ fun igbaradi Ife Ẹyẹ Agbaye, Russia 2018 nibi ti Victor Moses yoo ti darapọ mọ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: