Iléejọ́ Cameroon: Wọ́n Jẹ̀bi ẹ̀sùn ìṣelòdì sí ìjọba

Àwọn ajìjàǹgbara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ajìjàǹgbara náà ǹ jà fún òmìnira pátápátá fún àwọn olùgbé Cameroon lẹ́kùn ti wọn ti n sọ èdè Gẹẹsi

Ileẹjo ti ran awọn ajijangbara meje lọ sẹwọn fún ọdun mẹwaa si mẹẹdogun lori ẹ̀sùn iṣelodi si ijọba ati idunkooko-mọ-ni.

Ile ẹjọ naa ni awọn ajijangbara to n ja fun ominira agbegbe to n sọ ede Gẹẹsi nilẹ Cameroon, ko tẹlẹ ofin ilẹ naa.

Àkọlé àwòrán,

Ariwa-Iwọ oorun ati Guusu-Iwọ oorun ẹkun naa ni agbegbe meji ti wọn ti n sọ ede Gẹẹsi lorilẹ-ede naa

Ninu awọn ajijangbara ti wọn n ja fun ominira agbegbe Anglophone nilẹ Camaroon, naa ni olori wọn to tun jẹ akọroyin ni agbegbe Mancho Bibixy.

Awọn akọroyin ni igbohunsafẹfẹ Mancho Bibixy nii se pẹlu ijajagbara to n waye ni ẹkun ariwa-iwọ oorun ilu Bamenda.

Ariwa-iwọ oorun ati Guusu-iwọ oorun ẹkun naa ni agbegbe meji ti wọn ti n sọ ede Gẹẹsi lorilẹ-ede naa.

Àkọlé fídíò,

'Oúnjẹ ibìkan jẹ́ èèwọ̀ ibòmíì ni ọ̀rọ̀ ọmú ńlá'