Jega: Àwọn Asòfin Naijiria fẹ́ràn gbígba owó rìbá púpọ̀

Ile Igbimọ Asofin Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn Asòfin Naijiria fẹ́ràn gbígba owó ẹ̀bùrú

Alaga ajọ to ń rísí ètò ìdìbò Nàìjíríà (INEC) tẹlẹri, Ọjọgbọn Attahiru Jega, ni ọ̀nà àbáyọ ni ki a dẹ́kun rìbá gbígbà

Attahiru Jega ti fi ẹsun kan awọn Ile Igbimọ Asofin lorilẹ-ede Naijiria pe wọn fẹran lati ma a gba owo ni ọna ẹburu lati le se isẹ wọn.

Jega sọ ọrọ yii nibi to ti n se idanilẹkọọ lori ayajọ Ọjọ Iṣejọba Tiwantiwa (Democracy Day) tọdun yii ni Abuja lorilẹ-ede Naijiria.

Awọn to wa nibi idanilẹkọọ naa ni Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari; Aarẹ Ile Igbimọ Asofin, Bukọla Saraki; Abẹnugan Ile Asofin, Yakubu Dogara; Adajọ Agba lorilẹ-ede Naijiria; Walter Onnoghen ati awọn osisẹ ijọba lati oniruuru ẹka.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGbogbo ètò ti tò; Nàìjíríà ń pàdé DR Congo ni pọtá báyìí

Ọjọgbọn Jega fikun ọrọ pe awọn alaga igbimọ nile igbimọ asofin kọọkan fẹran lati maa gba owo lọna ẹburu lọwọ awọn eniyan.

Jega tun kilọ fun awọn eleto aabo lati rii wi pe wọn ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ lasiko idibo gbogboogbo ti ọdun to n bọ.