Iná Èkó: Kò sí ẹni to le dá okú rẹ mọ̀

Ile igbokusi ni Mainland
Àkọlé àwòrán ọ̀pọ̀ àwọn ebí ló bo ilé ìwòsàn Mainland bibà, lati wá àwọn olólùfẹ́ wọn.

Ìyàlẹ́nu ló jé lósàn ọjọ́ kejì tí ìsẹ̀lẹ̀ náà wáyé, nígbàti BBC Yorùbá sàbẹ̀wò sí ibùdó igbókúsí ilé ìwòsàn Mainland pé, àwọn ebí àwọn tó kú nínú ìjàmbá iná orí afárá ọtẹ́dọlá, tí kúrò níbẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIjamba ina Eko; Awakọ ni omi gọta lo yọ oun ninu ijamba ina

Awọn òṣìṣẹ́ náà sàlàyé pé, gbogbo àwọn òkú tí wọ́n gbé wá sibẹ̀ jóná kọjá ídámọ̀, èyí ló fáà tí wọn kò se gba ẹbi kankan láàyè láti gbe okú lọ̀, títí ti Gomina ìpínlẹ̀ Eko, Akinwumi Ambode yoo fi kéde bóya wọn yóò sín àwọn okú náà pọ̀ ní abi bẹ́ẹ̀kọ́.

Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn ebí ló bo ilé ìwòsàn Mainland bibà, lati wá àwọn olólùfẹ́ wọn.