FRSC: À ń ṣe ìwádìí lórí ẹni tó ní ọkọ̀ epo tó gbina.

Ọkọ tó ń jọ́ná
Àkọlé àwòrán O ní ìjọba tí gbé ìgbésẹ̀ láti fòpin sí ìrìnà àwọn ọkọ̀ epo yìí sùgbọn ọ̀pọ̀ wọn ń wá láti ẹ̀yìn odi tí wọn ò si ní ìwé ìrìna Èkó lọ́wọ́.

Kọmísọ́nà fún ọ̀rọ̀ tó ń lọ àti ìbáraẹni sọ̀rọ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkó, Kehinde Bamigbetan sàlàyé pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ina to jo lọjọbọ jẹ́ ohun tó bani ní inú jẹ́, sugbọn ìjọba ń gbìyànjú láti dín àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yí kù, kọ́da o ni ọ̀pọ̀ ẹ̀mi àwọn òṣìṣẹ́ LASMA lo ti n lọ síi látẹ̀yìn wá nítori àwọn awakọ̀.

Àkọlé àwòrán O ní ẹgbẹ́ àwọn sì ń ṣe ìwádìí láti mọ eni tí ó ni ọkọ̀ tó gbina náà.

Bamigbẹtan ní ìjọba tí gbé ìgbésẹ̀ láti fòpin sí ìrìnnà àwọn ọkọ̀ epo yìí sùgbọn ọ̀pọ̀ wọn ń wá láti ẹ̀yìn odi, tí wọn kò si ní ìwé ìrìnna Èkó lọ́wọ́.

O fikun pe ó tí pọn dandan fún àwọn ẹṣọ́ àlaabò lojú pópó láti ṣe ofin to tún nípọn fún àwọn awakọ epo, ti ìjọba pẹ̀lú yóò ríi dájú pe owó orí wọn yóò tún pọ̀ síi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba toun naa n ba BBC sọ̀rọ̀, ọ̀gá àgbà fajọ̀ ẹ̀ṣọ́ ojú pópó ní ìpínlẹ̀ Èkó, Hyginus Omejie, nínú àlàyé ti rẹ̀ sọ pé, gbogbo ìka ti ó bá ṣẹ̀ ní ọba yóò ge lori isẹlẹ ina ọhun, pàápàá jùlọ́ ilé iṣẹ́ tó ní ọkọ̀ epo tó gbina.

O ní bi ó tilẹ̀ jẹ́ pé ina ti bó gbogbo orúkọ ilé iṣẹ́ tó ni ọkọ̀ náà, síbẹ̀ ó ní àwọn yóò sàwárí rẹ̀ lórí àwọn ẹ̀rọ Kọmpúta láti mọ orúkọ ilé iṣẹ́ náà.

Omejie sọ pe, ìjọba Èkó ti pàṣẹ tẹ́lẹ̀ pé kí ọkọ̀ epo máà rìn lójú ọ̀sán mọ, nítori àwọn ǹkan to ti ṣẹlẹ̀ láti ẹ̀yìn wá, ti Femi Gbajabiamila si tí gbé àwọn kan lọ ilé ẹjọ fún irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tó wáyé ní Iyànà Ipaja.

Àkọlé àwòrán Ọ̀gá àgbà ẹ̀ṣọ́ ojú pópó ní ìpínlẹ̀ Èkó Hyginus Omejie nínú àlàyé ti rẹ̀ sọ pé gbogbo ìka ti ó bá ṣẹ̀ ní ọba yóò ge

Kíni àwọn ẹgbẹ́ àwakọ̀ Tanker ńsọ

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ́lu ikọ̀ iroyin BBC, asojú àwakọ̀ epo (NUPENG) tí ẹ̀ka Gúúsù Nàìjíríà, Tayo Aboyeji sàlayé pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná ọ̀hún jẹ́ ohun to bani nínú jẹ́ púpọ̀, tó si rọ ará ìlú lórúkọ àwọn awakọ̀ pé kí Ọ́lọ́run máse jẹ́ kí irú iṣẹlẹ̀ náà waye mọ.

Ní ti òfin pé kí awakọ̀ epo máa rìn lóru, o ní ó jẹ́ ohun ti ó lewu fun àwọn awakọ̀ nítorí wọn máa ń já ọkọ̀ gbà lọ́wọ́ wọn, ti wọn a sí pa àwọn awakọ míràn.

O ní ẹgbẹ́ àwọn sì ń ṣe ìwádìí láti mọ eni tí ó ni ọkọ̀ tó gbina náà