World Cup: ikọ̀ Spain náà ti dagbére fún Russia

àwọn agbaboolu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn ikọ agbábọ̀ọ̀lù méjééji ń tiraka lati duro ni Russia.

Ìyàlẹ́nu jùlọ lọ̀rọ̀ ọ̀hún jẹ́ fún gbogbo olólùfẹ́ bọọlù nínú ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó lọ lọ́wọ́ bí ní Orílẹ̀-èdè Russia se lé Spain tó gba ife lọdun 2010 kúro ninu ìdíje ọdún 2018.

Wọn na Spain fún igba àkọkọ ni ọdun méjìdinláàdọ́ọta sẹyìn ninu wòmi-ń-gba-sí ọ láti wo ipele kòmẹsẹ yọ.

Lẹ́yìn ti wọn lo àkoko wọn tan tí ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù méjèèjì ni ọ̀ọ̀mi ayò kan ní wọn ba fi wòmi-ń-gba-sí ọ mọ ẹni ti yóò dúró àti ẹni tí yóò lọlé