Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ekó tí kilọ fáwọn ọkọ̀ bẹtiróò láti gbàwé ìrìna

àwọn èèkan ijọb a ìpínlẹ̀ Eko Image copyright lagos state government
Àkọlé àwòrán Kọmisọna fun ìrìnà ní ìjọba kò ti kéde àsìkò ti ọkọ̀ epo bẹ́tiroo gbọd má rin

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó tí yan àwọn ọ̀nà tuntun fún àwọn awakọ̀ epo nípìnlẹ̀ Èkó gẹ́gẹ́ bíi ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìjàmbá ọkọ̀ epo bẹtiro to gba ẹ́mí ọ̀pọ̀ ènìyan tí ọ̀pọ̀ dúkìá náà sì sòfò pẹ̀lú.

Bákan náà ní wọn kìlọ̀ pé gbogbo ọkọ epo tí yóò bá wọ ìlú Eko gbọdọ̀ gbá ìwé ìrìnà pé wọn kún ojú òsùwọn pé àwọn sì ní ẹ́tọ́ àti rìn lójú pópó láàrín ọgbọ̀n ọjọ́ sí àsìkò yìí.

Lásìkò tí ó ń bá àwọn akọròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìfinúkonú pẹ̀lú àwọn tọ́rọ̀ kan, tó fi mọ ẹgbẹ òṣìṣẹ́ àwọn elépo (NUPENG) Kọmísọnà fún ìrìnà ọ̀gbẹ́ni Ladi Lawanson ní ìpinu ọ̀hún pọndandan lẹ́yìn ìwádìí lóri ìṣẹ̀lẹ̀ tó fi hàn pé ọkọ̀ tó gbé epo bẹtiro ọ̀hún ní àwọn kùdìẹkudiẹ kan pẹ̀lú àṣìṣe àwakọ̀ kó to bọ́ sí ojú pópó.

O kéde pé kí gbogbo ọkọ̀ epo ti yóò ba wọ ìlú Eko gbọdọ ní iwe ìrìna pé àwọn kú ojú òsùwọn lati rin titi, o ní wọn lè rí ìwé yìí gba láwọn ile isẹ irina ní ìpínlẹ̀ Eko.