Afrika Shrine: Emmanuel Macron sàbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Eko

Emmanuel Macron ati Muhammadu Buhari Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ààrẹ ilẹ̀ Faranse, Emmanuel Macron yóò dé sí Nàíjíríà ní Ọjọ́ Isẹgun, níbi tí yóò ti má a se ìpàdé pẹ̀lú Ààrẹ Muhammadu Buhari.

Aarẹ ilẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari yoo ma gbalejo Aarẹ ilẹ orilẹede Faranse, Emmanuel Macron fun ijiroro lori eto abo ati igbesunmọmi lorilẹede Naijiria.

Lasiko abẹwo rẹ, Macron yoo tun se abẹwo si ibi igbafẹ, ‘Afrika Shrine’ ni ipinlẹ Eko nibi ti olorin afro- juju, Fela Anikulapo Kuti da si lẹ, ti ọmọ rẹ, Femi Kuti si se atunse si, to si pe orukọ rẹ ni ‘New Afrika Shrine’.

Pẹlu abẹwo si ‘New Afrika Shrine’, Macron yoo jẹ aarẹ akọkọ ti yoo kọkọ wa si ile igbafẹ ti wọn mọ si agbegbe ti wọn ti n mu ogun oloro bi igbo, ati awọn obinrin ti wọn ki n wọ asọ to bo gbogbo ẹya ara wọn lati jo.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Macron yoo jẹ aarẹ akọkọ ti yoo kọkọ wa si ile igbafẹ ti wọn mọ si agbegbe ti wọn ti n mu ogun oloro bi igbo.

Lara awọn ayeye ti yoo ma waye ni ile igbafe naa ni, awọn olorin takasufe ti yoo ma lu ilu si awọn eniyan ni ibadi ati awọn alasọ alarabara ti yoo ma fi ẹwa wọn han nibi ayẹyẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLASTMA: Ẹ̀rí la nílò láti fi òsìsẹ́ tó ń gba rìbá jófin

Ohun to yẹ ki o mọ nipa aarẹ ilẹ Faransẹ, Emmanuel Macron

Lopin ọsẹ to kọja ni Aarẹ ilẹ Faranse naa, Emmanuel Macron darapọ mọ awọn adari awọn orilẹede to wa ni ilẹ Afirika, ni ipade ‘Ajọ Africa Union’ to waye ni olu ilu orilẹede Mauritania, Nouakchott.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iyawo Aarẹ Ilẹ Faranse, Brigitte Macron to jẹ olukọ rẹ Emmanuel Macron nigbati aarẹ naa wa ni ọmọ ọdun marundinlogun (15) , fi ọdun mẹrindinlogun (24) ju ọkọ rẹ lọ.
  • Emmanuel Macron di aarẹ ilẹ Faranse ni ọmọ ọdun mọkandinlegoji (39) gẹgẹbi aarẹ to kereju lati di aarẹ orilẹede naa.
  • Lẹyin ọdun marundinlogun ti Macron wa sisẹ ni ile isẹ to n soju ilẹ Faranse ni orilẹede Naijiria, o tun pada wa se ipade pẹlu Aarẹ Buhari ko to di wi pe yoo wa si ilu Eko.
  • Lọdun 2014 ni Macron da Minisita fun eto ọrọ aje ati idokowo labẹ Aarẹ tẹlẹri Francois Hollande to gba ipo lọwọ rẹ.
  • Aarẹ Macron faramọ ki ilẹ Faranse si wa pẹlu Ajọ Isọkan Ile Europe ‘European Union’, lẹyin ti awọn ti Ilẹ Gẹẹsi dibo lati kuro ninu ajọ naa, ti awọn alatako Macron si faramọ igbese naa.
  • Macron da ẹgbẹ ti rẹ silẹ fun eto idibo to gbe e wọle ni ilẹ Faranse.
  • Iyawo Aarẹ Ilẹ Faranse, Brigitte Macron to jẹ olukọ rẹ Emmanuel Macron nigbati aarẹ naa wa ni ọmọ ọdun marundinlogun (15) , fi ọdun mẹrindinlogun (24) ju ọkọ rẹ lọ.
  • Bakan naa, ki Macron to di aarẹ ile Faranse, o sisẹ fun ọdun mẹrin pẹlu ile ifowopamọ ni orilẹede naa.