Osisẹ báńkì Fidelity: Osu Kẹwa, ọdun 2017 lati gba owo osu kẹhin.

Osisẹ báńkì Fidelity: Osu Kẹwa, ọdun 2017 lati gba owo osu kẹhin.

Osisẹ Ile Ifowopamọsi Fidelity Bank, Sadiq Babatunde Sidiz, to sọrọ lorukọ awọn osisẹ yoku to n fapa janu, ni o ti pe Osu Mẹwa ti awọn ti i gba owo osu kẹyin lati ile ifowopamọsi, Fidelity.

Sidiz sisọ loju ọrọ yii nigba to n ba BBC sọrọ lasiko ifẹhọnu han wọn ni olu ileese Fidelity Bank to wa ni ipinlẹ Eko.

O sọ wi pe lẹyin ifẹhọnu han awọn lori aisan owo ajẹmọnu wọn ni ọdun to kọja, ni wọn yọ awọn ni isẹ bi ẹni yọ jiga, laisan owo ajẹmọnu wọn.

Osisẹ ile ifowopamọsi naa wa rọ adari agba ileese naa, lati yẹ ọrọ yi wo, nitori iya n jẹ awọn ọmọ wọn, ati ẹbi ati ara wọn.

Ọsẹ to kọja ni awọn osisẹ ile ifowopamọsi, Fidelity Bank se ifẹhọnu han lori aisan owo osu wọn fun osu mẹwa bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Banki Fidelity naa fesi lori ifẹhonu han awọn osisẹ yii

Wayi o, Adari eto ibanisọrọ fun ileesẹ Fidelity Bank, Charles Aigbe, nigba to n fesi si ẹsun naa, salaye pe awọn osisẹ to n fẹhọnu han naa, kii se osisẹ awọn, ati wi pe awọn ko jẹ osisẹ awọn kankan ni owo osu.

Charles fikun wi pe, awọn yoo gbẹ ẹsun naa lọ si ile ẹjọ ki ọrọ naa ba lee ni ọna abayọ to ba ofin mu.