Ọlọ́pàa dóòlà ẹ̀mí fadá mẹ́rin lọwọ àwọn ajínigbé

Awọn alufaa ijọ Aguda
Àkọlé àwòrán,

Awọn alagba ijọ aguda lorileede Naijiria ti pe fun iwọde lori ipenija ipaniyan to peleke

Orin ọpe ti gba ẹnu awọn ọmọ ijọ Katoliiki ilu Edo ati Warri pẹlu iroyin to gbode pẹ awọn ọlọpaa ti ribi doola ẹmi awọn alufaa ijọ aguda mẹrin lọwọ awọn ajinigbe.

Andrew Aniamaka to jẹ alukoro fun ile iṣẹ ọlọpa ni ipinlẹ Delta lo fidi ọrọ na mulẹ fun ile isẹ BBC pe lootọ ni awọn fada naa ti gba itusilẹ.

Rev Fr Nike Onyanofoh to jẹ alagba ijọ aguda fun ẹkun Benin naa so wi pe wọn ti gbe awọn alufa naa lọ si ile iwosan ni Benin fun itọju to peye.

Oríṣun àwòrán, Catholic Church Nigeria

Àkọlé àwòrán,

Àwọn fada naa lugbadi awọn ajinigbe nigba ti wọn n lọ ilu Ekpoma ni Ipinlẹ Edo fun ayẹyẹ kan

Ewe,Komisana ọlọpa nipinlẹ Delta Mustafa Muhammed ni ọwọ awọn ti tẹ diẹ lara awọn afunrasi naa.

Ohun ta gbọ ni pe ṣe ni awọn afunrasi to jin awọn alufaa na gbe fẹsẹ fẹ nigba ti wọn ko firi awọn ọlọpaa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn alufaa ijọ aguda mẹrin ti wọn lugbadi ajinigbe ni Ìjọba Ibilẹ Ethiope ni Ipinlẹ Delta lọjọru ni awọn ajinigbe ohun ti saaju beere ọgọrun miliọnu Naira lati tu wọn silẹ.

Awọn ti wọn ji gbe naa ni Fada Victor Adigboluja ti ẹkùn Ijebu Ode, Fada Anthony Otegbola ti ẹkùn Abeokuta, Fada Joseph Idiaye ti ẹkùn agba ti Benin ati Fada Obadjere Emmanuel ti ẹkùn Warri.

Oju awọn alufa ij aguda ri to lọwọ ajinigbe ni 2018

Ko ti ju ọsẹ mẹta lọ ti wọn ji awọn obinrin ijọ aguda ti wọn yàn lati má lọkọ marun un gbe ni Ipinlẹ Delta nigba ti wọn n ti ibi isinku kan bọ.

Ohun ta gbọ ni wi pe ṣadede lawọn agbebọn yọ si awọn obinrin naa ti wọn yinbọn lu ọkọ wọn ti si jin wọn gbe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ohun ti oju awọn alufa ijọ aguda ni Naijiria ri lọwọ awọn ajinigbe kọja afẹnusọ

Alukoro ọlọpaa Andrew Aniamaka sọ pe lẹyin ọsẹ meji ni wọn to tun wn silẹ ti ọwọ awn si ti tẹ afunrasi kan.

Aniamaka kọ lati sọ boya wọn san owo lati fi doola ẹmi wọn.

Ni ọsu kini ọdun yi ni awọn alagba ijọ aguda panupọ lati bẹnu atẹ lu bi ijinigbe ati ipaniyan ti ṣe peleke lorileede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Ọjọ buruku ni ọjọ ti awọn afunrasi pa alufa ijọ aguda nipinlẹ Benue.

Iku awọn alufa ijọ meji kan ni ipinlẹ Benue lọwọ awọn afunrasi darandaran lo ṣe okunfa igbesẹ yi.

Laarin ọjọ kẹtala Oṣu kọkanla ọdun 2017 si ọjọ kẹfa oṣu kini ọdun 2018, awọn ajinigbe ti jin awọn obinrin ijọ aguda mẹfa gbe.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Ilé ẹjọ́ dája ikú fáwọn ajínigbé ni Benue

Ni oṣu keje, ọdun 2018, ile ẹjọ kan ni Ipinlẹ Benue dajọ iku fun awọn ajinigbe meji kan ti wọn ji alufaa ijọ Aguda kan gbe ni ipinlẹ naa, ti wọn si paa, lẹyin ọdun meji ti wọn ṣiṣẹ laabi naa.

Àkọlé àwòrán,

Awọn mẹji ti wọn dajọ iku fun nitori pe wọn ji alufaa John Adeyi gbe

Oṣu kẹfa, ọdun 2016 ni awọn ajinigbe naa ji alufaa Adeyi to jẹ alufaa agba fun diọsisi Otukpo ni Ipinlẹ Benue gbe. Nigba ti awọn agbofinro maa wa alufaa naa ri ni oṣu meji lẹyin rẹ, oku rẹ to ti jẹra ni wọn ri.

Oríṣun àwòrán, Catholic Diocese of Otukpo

Àkọlé àwòrán,

Oṣu kẹfa ọdun 2016 ni wọn ji alufaa Adeyi to jẹ alufaa agba fun diọsisi Otukpo ni Ipinlẹ Benue gbe

Awọn mẹrin ni ọlọpàá mu nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ. Wọn ni wọn tilẹ kọkọ gbowo lọwọ awọn ẹbi alufaa naa bii pe wọn fẹ fi silẹ.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police

Àkọlé àwòrán,

Awọn mẹrin ti wọn mu fun iku alufaa John Adeyi

Ni Ọjọru ni adajọ kan ni ile ẹjo kan ni Markudi dajọ iku fun awọn méji lara wọn. Adajọ ni, wọn yoo pa wọn pẹlu okun lọrun wọn ni.