2019 Elections: Oshiomole ní Buhari yóò wọlé láìsí àtìlẹ́yìn Ọbasanjọ

Adams Oshiomole
Àkọlé àwòrán,

Oshiomole gbá kuru ti àwọn olóyè ẹgbẹ́ APC

Alága àpapọ̀ fẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress APC, Adams Oshiomole sọ pe, igbesẹ aarẹ ana Oluṣẹgun Obasanjọ lati fi ẹnikẹni jẹ aarẹ orilẹede orilẹede Naijiria ninu idibo ọdun 2019 ko le ṣeeṣe.

Oshiomole sọrọ yii nibi ipolongo oṣelu ẹgbẹ APC nilu Kano, nibi to ti n ki awọn ti wọn ṣẹṣẹ darapọ mọ ẹgbẹ APC latinu ẹgbẹ oṣelu alatako PDP, kaabọ sagbo ẹgbẹ naa.

Alaga apapọ fẹgbẹ APC sọrọ pẹlu idaniloju pe, aarẹ Muhammadu Buhari yoo jawe olubori ninu idibo aarẹ ọdun 2019 laisi atilẹyin Obasanjọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Adedoyin: Tí mo bá rí Buhari, màá sọ fun kó rántí pé Ọlọ́run wà

Lori iwe ti ẹgbẹ PDP kọ si ajọ iṣọkan agbaye pe, ijọba amunisin nijọba Buhari to wa lode, Oshiomole ni ko si ohun to jọ bẹẹ.

O ni Obasanjọ gan an lo bẹrẹ ijọba amunisin lorileede Naijira nigba ti o ṣe ijọba gẹgẹ aarẹ.

Oshiomole tun fikun ọrọ pe, ẹgbẹ oṣelu APC ko ṣeleri lati tun orilẹede Naijiria ṣe laarin ọdun mẹrin, nitori ko rọrun lati tun ohun ti ẹgbẹ PDP ti bajẹ fun ọdun mẹrindinlogun ṣe laarin ọdun mẹta ati aabọ.

Oshiomole pajúdà sí àwọn olóyè ẹgbẹ́ APC

Ìkéde Oshiomole kò ṣẹ̀yìn ìròyìn kan to gbòdé pé àwọn tọ́rọ̀ kan tó fi mọ àwọn to sún mọ ààrẹ Muhammadu Buhari àti àwọn gómínà míràn tí kò dárúkọ ń pinu láti yọ òun kúrò lẹ́gbẹ̀.

Ó ni ẹ̀gbìnrìn ọ̀tẹ̀ wọn kò sẹ̀yìn àwọn ìgbésẹ̀ tó ń gbé láti mú àtúntò bá ẹgbẹ́ òṣèlú APC kó lè ni ipa rere.

Àwọn ẹ̀sùn náà jẹ́yọ nínú àtẹ̀jade kan ti akọ̀wé rẹ̀ Simon Ebebgulem fọwọ́si nílùú Abuja.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ ọ́, ipò àwọn tọ́rọ̀kàn nínú tí di mímọ̀ láìpẹ́ yìí lásìkò tí olùdíje fún ipò ààrẹ tẹ́lẹ̀rí Alhaji Mumakai Unagha.

Unagha gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, 'ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò ní jáwé olúbori níwọ̀n ìgbà ti Adams Oshiomole bá ṣì jẹ́ alága àpapọ̀ ẹgbẹ́'.

Saraki: Kàkà kí Oshiomọlẹ sọ̀rọ̀ gidi, èpè ló ń sẹ́

Àkọlé àwòrán,

Saraki ni oun kmo ni kọwe fipo silẹ

Olori Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà, Bukola Saraki bẹnu àtẹ lu bi alagba ẹgbẹ oṣelu APC, Adams Oshiomhole ṣe ni pe ko kọwe fipo silẹ latari bi o ṣe kuro ninu APC lọ PDP.

Saraki sọ ninu atẹjade kan lati ọwọ agbẹnusọ rẹ Yusuph Olaniyọnu l'ọjọ Abamẹta pe, ko da, miliọnu kan Oshiomhole ko le le oun kuro nipo.

O ni, "Iyalẹnu lo jẹ pe Ogbẹni Oshiomhole n ṣe bi adiyẹ ti ojo pa, to si n su ẹkun kakakiri ilẹ bi ẹni pe olori ile igbimọ aṣofin agba ni oku to n le e kiri."

Àkọlé fídíò,

Olóṣelú máa ń wá ẹgbẹ́ ti wọn lè lò láti mu ìpinu wọn ṣẹ

Saraki ni ala lasan ni awọn to ni ki oun kọwe fipo silẹ n la.

O tun ṣalaye wipe kaka ki Oshiomhole sọrọ gidi, ṣe ni oun lo eebu ati epe.