Ọọ̀ni Ogunwusi: Irọ́ ni àhésọ pé mo ní olorì tuntun

Ọọni ti Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi Image copyright Ooniadimulaife/Instagram
Àkọlé àwòrán Ọọni Ogunwusi ni oun ko ti ni Olori

Ọọni Ile-Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi ni ko si ootọ kan ninu ahesọ pe oun ti mu olori tuntun wọ aafin.

Ọmọọba Jide Fadairo to ṣe agbẹnusọ rẹ gbe atẹjade kan sita ni ọjọ Aiku ninu eyi to ti sọ pe ko ṣeeṣe ki oba naa mu iyawo ni ikọkọ.

O ni, "Kii ṣe idile ọba nikan ni yoo mọ si iru igbeyawo bẹẹ. Awọn aṣa ilẹ Yoruba gbudọ farahan ni iru igbesẹ bee. Oriṣiriṣi orukọ olori tuntun lati n gbọ, sugbọn ko si otitọ kan nibẹ."

Ẹ o ranti wipe, oṣu kẹjọ ọdun 2017 ni igbeyawo ọba naa f'ori sanpọn. O ti wa lai ni olori lati igba naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌọni Ogunwusi Adeyẹye pe fun itọju awọn ọdọ