Ọọni ṣílé tuntun fáwọn ọmọ òrukàn n'ílù Ibadan.

ọni Ile-Ifẹ Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi,
Àkọlé àwòrán,

Ajo ẹlẹyinju aanu ni Ọọni Ogunwusi da silẹ

Ọọni Ile-Ifẹ Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi, Ọjaja keji ti dẹrin pa ẹkẹ awọn ọmọ orukan atawọn ọmọ to ku diẹ kaato fun nilu Ibadan lọjọ aiku, nibi iṣile tuntun fawọn ọmọ orukan.Ajo ẹlẹyinju aanu ti Ọba Alayeluwa naa da silẹ, Hopes Alive Innitiatives (HAI)" wa lati ri daju wipe gbogbo ọmọ orukan ati awọn to kudiẹ kaato fun lo bẹrẹ sini gbayegbadun, eyi lo mu ki ajọ naa maa lọ lati ipinlẹ de ipinlẹ ninu igbiyanju ati wa ojutu si iṣoro irufẹ awọn eeyan bẹẹ."

Lasiko to n sọrọ nibi ajọyọ isile naa ni agbegbe Ọmí nilu Ibadan, Ọba Enitan, eni ti Agbolu ti Ilu Agbaje Ọba Adekunle Adebọwale soju fun fi idunnu rẹ han fun aṣeyọri akanṣe iṣẹ naa.

O ṣe alaye wipe gbogbo ẹni ti Eleduwa ṣẹgi ọla fun lo ni ojuṣe ati se iranlọwọ fun awọn eeyan to kudiẹ kaato fun.O ni, "gbogbo ẹni to ri taje ṣe lo yẹ ki o ṣe awokọṣe ajọ ẹleyinju aanu yi, ki aye le dẹrun fun gbogbo eyan ti ara n ni."

Àkọlé àwòrán,

Ọba Adekunle Adebọwale lo ṣoju Ọọni

Ninu ọrọ tiẹ, igbakeji oludasile ajọ ẹlẹyinju aanu naa, arabinrin Temitọpẹ Morẹnikẹ Adeṣẹgun ṣe alaye wipe Ọọni Ile-Ife Ọba Ogunwusi ṣe agbekale ajo naa pẹlu ajọṣepọ awọn lajọlajọ mii ti kiiṣe tijọba fun anfani awọn ọmọ orukan ati awọn to kudiẹ kaato fun lojunna ati le fun igbe aye wọn ni itumọ ati ibẹrẹ ọtun.

O tẹsiwaju wipe akanṣe iṣẹ naa ko se e da ṣe fun Ọọni Ile-Ife ni kan, labẹẹ bẹẹ lofi keesi gbogbo ẹni ti nnkan rọrun fun lati fi ifẹ han nipa fifọwọ sọwọpọ pẹlu ajọ naa.O ni, "Ati ẹni to lowo, ati ẹni ti o toṣi, Ọlọrun lo da gbogbo wa. Ti Ọlọrun ba si fẹ ṣe ni loore, eeyan naa ni yoo lo. Nitori idi eyi ni a fi n keesi gbogbo ẹlẹyinju aanu lati fi ifẹ han si awọn to kudiẹ kaato fun."

Àkọlé àwòrán,

Ile ti Ooni ko fun awọn ọmọde naa

Alamojuto ile awọn ọmọ orukan naa, arabinrin Victoria Adeleke dupe lọwọ Ọba Ogunwusi fun idasilẹ ajo ẹlẹyinju aanu naa, gẹgẹ bi o ṣe parọwa si ọgọrọ awọn eeyan to lowo lọwọ lati se awokọṣe Ọọni Ile-Ife.