Yẹmi Ọsinbajo: Àsìkò kò tíì kan Yẹmi láti di ààrẹ Nàìjíríà

Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ Osinbajo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Bi o tilẹ jẹ pe Ọṣinbajo kii ṣe eeyan to n lepa ariwo ṣekarimi, sibẹ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ko ye kokikii eto iṣakoso rẹ

Ore-ọfẹ ati anfani ifẹ nla ni igbakeji aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Yẹmi Oṣinbajo n jẹ bayii laarin awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria.

Eyi si jẹ ohun to Jẹ kayeefi diẹ nitori irufẹ anfani ifẹ bayii kii wọpọ fawọn oloṣelu lorilẹ-ede Naijiria nitori aṣọ iyi ọpọ lo ti ya.

Ko si idi meji tawọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria fi n kan saara si Ọjọgbọn Oṣinbajo, ju awọn igbesẹ akọ to gbe lasiko to fi n dele fun aarẹ Muhammadu Buhari fun ọjọ mẹwaa to lọ lo fun isinmi laipẹ ati latẹyin wa.

Amọ ṣa, gẹgẹ bii oloṣelu to wa lati ẹkun guusu orilẹ-ede Naijiria, ko daju pe Ọṣinbajo yoo lee dide dije fun ipo aarẹ lasiko idibo apapọ ọdun to n bọ, nitori ilana yan-ki-n-yan eleyi ti wọn fi le ori eto idipo-mu laarin ẹkun ariwa ati guusu orilẹ-ede naa.

'Ipaniyan ati ifiyajẹni lọna ti ko bofinmu lọwọ awọn ọlọpaa'

Laipẹ yii ni Ọjọgbọn Ọṣinbajo paṣẹ atunto ikọ agbenawoju awọn adigunjale, FSARS ti o ti di atobi-maṣee-bawi bayii nitori oniruru ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi n kan wọn.

O ti le ni ọdun kan ti ariwo gbami-gbami araalu ko ti jẹ ki eti Aarẹ Muhammadu Buhari di si ọkan-o-jọkan iwa kotọ lọwọ awọn ọlọpaa ikọ naa.

Sugbọn Ọṣinbajọ ṣalaye pe, gbọnmọ-gbọnmọ iroyin iwa aṣemaṣe awọn oṣiṣẹ ikọ naa lo ṣokunfa aṣẹ atuntun ti oun pa, eleyi to si di iroyin ayọ nla fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, paapaa julọ lori ikanni ayelujara Twitter.

Ṣaaju ni igbakeji aarẹ orilẹ-ede Naijiria naa, ti kọkọ yọ olori ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS fun bi awọn oṣiṣẹ ikọ naa ti ṣe ṣigun bo ẹka ile aṣofin apapọ.

Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ lo n fi oju atobi-masee-bawi wo Lawal Musa Daura, to jẹ ọga agba ileeṣẹ naa, nitori ọkan o jọkan iwa fami-lete n tutọ wọn, ti awọn kan si ti n beere idi gan ti o fi ṣoro fun aarẹ Buhari lati rọọ loye.

Amọ ṣa, Oṣinbajọ ko beṣu-bẹgba to fi yọ Daura nipo bi ẹni yọ jiga.

Kini Oṣinbajo ti ṣe tẹlẹ?

Eyi kọ ni igba akọkọ ti aarẹ Buhari yoo maa lọ fun isinmi, ti igbakeji rẹ yoo si maa gbe awọn igbesẹ to loorin eleyi ti awọn eeyan ti pariwo kare fun un.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ọpọ lo n fi oju koṣee bawi wo Lawal Musa Daura to jẹ ọga agba ileeṣẹ DSS tẹlẹ nitori ọkan o jọkan iwa familete n tutọ wọn

Ni ọdun to kọja ti aarẹ Buhari lọ gba isinmi, lasiko naa ni eto ọrọ aje Naijiria n ṣojojo ti owo dọla di ọwọngogo ni Naijiria, ṣugbọn ni gẹlẹ ti Oṣinbajo di adele aarẹ lo ti gbe awọn igbesẹ kan ninu eyi ti a ti ri aṣẹ to pa fun banki apapọ lati fọn dọla tuntun si inu ọja ọrọ aje eyi si fun Naira ni ifẹsẹmulẹ to duro deede nigba naa.

Kini araalu n sọ̀?

Bi o tilẹ jẹ pe Oṣinbajo kii ṣe eeyan to n lepa ariwo ṣekarimi, sibẹ awọn eeyan Naijiria ko ye kokikii eto iṣakoso rẹ.

Pẹlu gbogbo ariwisi to n dojukọ Ọ́sinbajo lori bi o ṣe n gbe awọn igbesẹ naa saara loriṣiriṣi, ọpọ gba pe, o hande pe, ero rẹ rọ mọ ti aarẹ Buhari lori gbigbogun ti iwa ijẹkujẹ, awọn agbebọn Boko Haram ati igbesẹ to n gbe lati yẹ awọn ẹka ọrọ aje miran wo yatọ si epo rọbi.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari ti sọ pe oun yoo tun dije lẹẹkan sipẹlu igbakeji oun, ko si daju pe Oṣinbajo ṣetan lati figagbaga pẹlu ọga rẹ yii

Nibayii, eto idibo apapọ nkan lẹkun gbọngbọngbọn bayii lorilẹ-ede Naijiria, ọpọ lo si ti n woye bi yoo ti dun to kani igbakeji aarẹ, Oṣinbajo lee kuku di aarẹ gan an ni ṣan an!

Amọ, ala lasan ni eleyi, ko si bi o ṣe lee wa si imuṣẹ laipẹ-bẹẹni Ọjọgbọn Oṣinbajo pẹlu ko fi igba kọọkan sọrọ pe oju oun wa lori aga naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aarẹ Buhari ti sọ pe oun yoo tun dije lẹẹkan si.

Lootọ ko daju pe Oṣinbajo yoo dije fun ipo aarẹ ni ọdun 2019 ṣugbọn pẹlu ọjọ ori rẹ aaye ṣi lee ṣi fun un ni ọdun 2023 nigba ti ọpọn yoo sun kan ẹkun guusu Naijiria lati gori ipo naa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ Aarẹ, Garba Shehu, ni bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe jawe olu bori ni ipinlẹ Katsina, Bauchi ati Kogi ni awọn idibo to waye nibẹ fi han pe, Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ Yemi Osinbajo yoo jawe olubori ni idibo 2019.

Shehu sọ pe yatọ si awọn ipinlẹ mẹta yii, iṣesi APC ni ipinlẹ Ekiti ati Cross River fi han pe inu ara ilu dun si ẹgbẹ naa gan-an ni.

'Awọn ọmọ Naijiria ti sọrọ bayii. Awọn esi ibo wọnyii fi han pe aṣeyọri daju. Ẹgbẹ APC yoo koju ibo gbogbogbo ti ọdun to n bọ pẹlu ifọkanbalẹ.'

O tẹsiwaju pe ko si aaye fun oṣelu ''bun-mi-n-bun-ẹ, eleyi ti a mọ ẹgbẹ PDP fun."

Image copyright Getty Images

Bakan naa lo tun rọ ile igbimọ aṣofin lati fọwọ sowọpọ pẹlu ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ki isakoso ijọba baa le gun rege.

Garba Shehu to sọrọ lori rira ibo sọ pe ẹṣe nla ni iru iwa yii jẹ niwaju ofin ati pe, ẹni to ba ni ẹri, ki o muu lọ sọdọ awọn agbofinro.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAPC Convention: Ààrẹ Muhammadu Buhari ti dé sí Gbọ̀gàn ìdìbò