Bàbá Elo: Olúwaṣeun, ojú èmi àti ọmọ mi túnra rí lẹ́ẹ̀kan síi!

Image copyright @ritasoulofficial
Àkọlé àwòrán Ọmọ ẹni ku san ju ọmọ ẹni nù lọ; Elo di àwàrí fún obi ẹ

Elo, ọmọ ọdún mẹ́rin di rírí nilu Benin.

Elo ni wọn ri nile ọmọ alainiya kan nilu Benin nipinlẹ Edo ni guusu Naijiria nibi ti ẹnikan ti kẹ́fín pe o jọ ọmọ ti wọn n wa kiri lori érọ ayelujara.

Aago mókanla owurọ ọjọ kọkanla, oṣu keje ni wọn ti ń wa Elo Ogidi to dawati nile ijọsin kan nipinlẹ Eko.

Image copyright @ritasoulofficial
Àkọlé àwòrán Olorun kò má jẹ ki ọmọ wa sọnu

Gbogbo ọna ni tẹbi-tara ti fi n gba wa paapaa lilo ẹrọ ayelujara loju opo twitter, facebook ati bẹẹbẹẹlọ.

Bakan naa nile ijọsin ati ẹgbẹ loriṣiiriṣii gbe ohun ẹ̀bẹ̀ soke pe ki wọn ri Elo pada nitori pe ko yẹ ki ọmọ ẹni sọnu rara ki a to sọ pe nile ijọsin.

Image copyright @afokoghene
Àkọlé àwòrán Omọ ti wọn n wa nile ijọsin di awari

Lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2018 ni Oluwa nu omije wa nu ti a ri ọmọ wa ni ọrọ Baba Elo nigba ti obinrin kan deede pe aago ti wọn fi nọma rẹ si oju opo twitter pe oun ri ọmọ kan to jọ aworan Elo.

Kia ni wọn gbe igbese pipe ọlọpaa ti wọn si ṣiṣẹ won bi iṣẹ eyi to mu Elo pada wale bayii.

Pẹlu ariwo ayọ nla ni Elo fi gbohun Treasure, egbọn rẹ lori ẹrọ ibanisọrọ ki wọn to rira.

Rita Grace ati Afokoghene Ogidi ti wọn jẹ iya ati baba Elo ni wọn ti gbe igba ọpẹ́ pe àwọn yoo le ṣe ayẹyẹ idupẹ ọjọ ibi ọmọ wọn to sọnu ti yoo waye lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii.

Inu ọpọlọpọ lo dun pe Elo di awari ti obinrin n wa nkan ọbẹ̀ bẹẹ wọn gba imọran pe ki gbogbo obi ati alagbatọ tọju ọmọ wọn daadaa paapaa lasiko isinmi yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMori ara mi to funfun, mi o mọ pe ẹtẹ ni
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAsigbe awọn ọmọkunrin meji ni India

Gbogbo ojulumọ lo ba wọn dawọ idunnu pe ori kó Elo yọ pada wa sile. Awọn oju opo ayelujara ti wọn fi pin aworan rẹ naa ni awọn eniyan ti n dupe fun Olodumare ti wọn n ki ẹbi Ogidi ku oriire.