America: Àìsàn jẹ̀jẹ̀rẹ̀ pa Sẹ́nétọ̀ John McCain l'ọmọ ọdún 81

Aarẹ tẹlẹri Barack Obama ati Sẹnetọ John McCain Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Obama ṣọfọ McCain ti wón jọ du ipo aare America

John Mc Cain ni o ba Obama jọdu ipò aarẹ America lọdun 2008.

Ọkan gboogi ninu awọn oloselu ni ilẹ Amẹrika, John McCain ti dagbere faye ni ọmọ ọdun mọkanlelọgọrin.

John McCain jẹ oloṣelu to ni igboya lati ja fun ohunkohun to ba gbagbọ ninu rẹ de opin.

Awọn mọlẹbi rẹ to fi iroyin naa lede sọ pe ati ẹbi ati ara lo wa lọ́dọ̀ akinkanju naa nigba to papoda. America pàdánù ọ̀kan gbòógì nínú olósèlú wọn.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọjọ Satide ní àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ní sẹ́nétọ̀ náà pinnu láti máse gba ìtójú àìsàn jẹjẹrẹ mọ́ nítorí ọjọ́ orí rẹ̀.

Ọjọ Satide ní àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ní McCain pinnu láti máṣe gba ìtójú àìsàn jẹjẹrẹ mọ́ nítorí ọjọ́ orí rẹ̀.

John McCain to fi aye silẹ ni Ọjọ Satide, Osu Kẹjọ, ọdun 2018 ni aisan jẹjẹrẹ ọpọlọ ba finra fun ọpọlọpọ ọdun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mi o fẹẹkan ni mo fẹ dupo aarẹ'

Awọn adari gboriyin fun John McCain to papoda

Awọn oloselu ati ọtọkulu ni awujọ ilẹ Amerika ati kaakiri agbaye ti ba ẹbi ati ara Sẹnetọ John McCain kẹdun lori iku akinkanju naa.

Aarẹ àná, Barack Obama, ti wọn jọ dije dupo aarẹ ni ọdun 2008 sọ wi pe akinkanju eniyan ati ajafẹtọ ọmọniyan saaju ifẹaraẹni ni McCain to papoda naa.

Awọn ọrẹ rẹ ati ojulumọ rẹ, Joe Biden ati Aarẹ tẹlẹri George W Bush se apejuwe McCain gẹgẹbi olufẹ ara ilu ati asa ati ise to mu ilosiwaju dani.

Amọ iroyin kan sọ wi pe sẹnetọ John McCain sọ ninu iwe ikeyin rẹ wi pe Aarẹ ilẹ Amerika, Donald Trump kò gbọdọ wa si ibi ayẹyẹ ikẹyin oun.

John McCain fikun pe Aarẹ Barack Obama gbọdọ wa lara awọn ti yoo sọ ọrọ ikẹyin nipa oun ni ibi ayẹyẹ isinku oun.

Tani Sẹneto John McCain?

John McCain jẹ akinkanju ajagunfẹhinti ogun Vietnam to pada wa di ọkan gboogi lara awọn oloselu ni ilẹ Amerika.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọdun marun un ni McCain fi jẹ ẹlẹwọn ogun Vietnam, ti o si jẹ orisirisi iya ni ọwọ awọn ti o mu u pamọ.

Ọjọ kọkandinlọgbọn, ọdun 1936 ni ibugbe awọn ologun oju omi ni Coco Solo Naval Air Station ni wọn ti bi John McCain.

Ọdun marun un ni McCain fi jẹ ẹlẹwọn ogun Vietnam, ti o si jẹ orisirisi iya ni ọwọ awọn ti o mu u pamọ.

Saa mẹfa ọtọọtọ ni Sẹnetọ John McCain fi jẹ sẹnetọ, ti o si dije dupo fun Aarẹ ilẹ Amerika labẹ ẹgbẹ oselu Republican ni ọdun 2008.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMori ara mi to funfun, mi o mọ pe ẹtẹ ni
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMegabite: Ilé-ìwé ni mo ti bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ