Mo lé fi òjò dá àrà tò wù mi f'áwọn oníbárà mi lásìkò tó wù mí

Godwin
Àkọlé àwòrán,

Ǹjẹ́ o mọ pe eniyan máa n pe ojo?

Iṣẹ́ Ọlọrun àwámárídìí ni káàkiri àgbáyé

Kìí ṣe òni ní a ti máa ń gbọ nípa àwọn alagbara ayé l'ókùnrin àti l'obinrin, àwọn aláwo ti wọn máa ń ṣe oníruuru òògùn, ti omíran a sì máa sọ pé oun le ti òjò tàbi yí oju ọja padà.

Àkọlé àwòrán,

Agbára ju agbára lọ: Wo bàbá Godwin to pe òjò

Awọn ènìyàn míràn máa ń mú kí òjò rọ lásìkò tí wọn bá ń fẹ, ti àwọn ènìyàn sì máa ń kà wọn kún alágbara ẹ̀dá tó lè mú kí òjò rọ tàbí kí òjò dá.

Àkọlé fídíò,

Wọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn míràn ní ìgbàgbọ pé ènìyàn kò lè mú ki òjò rọ tàbí dí òjò lọ́wọ́ tí àwọn àjọ tó ń ri sí bí ojú ọjọ́ ṣe rí (NIMET) pẹ̀lú sọ pé kò sí eni tó lè dán irú ẹ wò.

Sùgbọn nínú ìwádìí BBC a ri i pé àwọn tó ń ti òjò ti wọn sì ń ṣí òjò pọ̀ jántìrẹrẹ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Àkọlé àwòrán,

Sùgbọn nínú ìwádìí BBC a ri pé àwọn tó ń ti òjò ti wọn sì ń sí òjò pọ̀ jántìrẹrẹ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Iṣẹ́ wọn ni láti tí òjò fún àwọn tó bá ni ìnáwo láti ṣe, yálà òkú àgbà, ìgbéyàwó tàbí láti lọ ta ọjà wọn, nínú ìwádìí BBC wọn tún ni àwọn míràn máa bẹ̀wọ́n lọ́wẹ̀ láti jẹ́ kí òjò rọ̀ níbí ayẹyẹ ọ̀tá wọn.

Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní èrò ṣe fún àwọn míran nítorí wọn gbàgbọ́ pé ọgbọ́n àrékérekè lásán ní àti pé kò sí ẹni to lè tú iṣẹ́ olúwa wò nípa rírọ òjò tàbí dídáa dúró.

Àkọlé àwòrán,

Mo lé rán òjò dí ilé ọ̀tá àwọn alábara mi

Pẹ̀lú ìrànwọ àwọn ènìyàn àkòròyìn BBC sàbẹ̀wò sí Godwin Onasedu ní ìlú Ifitedunu, ni ìjọba ìbílẹ̀ Dunukofia ìpínlẹ̀ Anambra, Okùnrin yìí jẹ́ a mú òjò rọ.

Àkọlé àwòrán,

Lẹ́yìn ìpèsè gbogbo ǹkan wọnyìí Godwin rọ ojò lẹyìn wákatí méjì, ti ojò náà rọ fun ìṣẹ́jú márùn kó to dá., òjò náà kò lágbára púpọ̀.

Nínu àlàyé rẹ̀, o ni iṣẹ́ ti ìran oun ni oun ń ṣe láti ìgbà ìwáṣẹ̀ ṣùgbọn láti mú òjò rọ̀ àwọn nílò.

  • Kírìtì Oti Méjì
  • Ìgò ògógóró 501 kan
  • Obì ẹyọ mérin
  • Ẹgbẹ̀rún kan Náírà láti la obì
  • Kándu, àṣọ funfun àti pupa

Lẹ́yìn ìpèsè gbogbo ǹkan wọnyìí Godwin rọ ojò lẹyìn wákatí méjì, ti ojò náà rọ fun ìṣẹ́jú márùn kó to dá., òjò náà kò lágbára púpọ̀.