Ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ ni wọ́n fi kan Les Moonves ti CBS

Moonves Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọ̀gá ilé iṣẹ́ kọ̀wé fipò sílẹ̀ fún ẹsun ìbálòpọ̀

Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ̀ ìròyìn lórílẹ̀-èdè Amẹrikà tí kọ̀wé fipò sílẹ̀ lẹ́yìn ti wọn fẹ̀sùn ìbálòpọ̀ kàn-an.

Ilé iṣẹ́ ìròyìn CBS tí ń ṣe ìwádìí Les Moonves lẹ̀yìn tí ìwé ìròyìn New Yoker gbé ọrọ kan jáde ní oṣu keje ọdun (July).

Awọn eeyan tí fesun tuntun míràn kan an nígbà ti àwọn obinrin mẹ́fà kan tún jáde lọ́jọ́ Àìkú láti fẹ̀sùn ìbálòpọ̀ kàn-án.

Ọgbẹ́ni Moonves tó jẹ́ ẹ́ni ọdún mẹ́jìdínlààdọ́ta sàlàyé pé irọ́ ni wọn pa mọ oun àti pe ohun ti kò ṣe gbọ́ séti ni ọ̀rọ̀ náà.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Les Moonves jẹ́ ọkan lára àwọn alágbára jùlọ lorílẹ̀-èdè Amẹrika

Ẹ̀wẹ̀, ile iṣẹ ìròyìn CBS sọ pé àwọn àti ọ̀gbẹ́ni Moonves yóò ṣe àgbékàlẹ̀ ogún mílíọ̀nù dọ́là fún ẹ̀gbẹ́ #Ati emi náà (#Me Too).

Nínú àtẹ̀jáde tí ilé isẹ́ CBS fi síta ló ti sàlàyé pé ọgá àgbà náà yóò fíṣẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alákoso ní wàrànsesà.

Joseph Lanniello ni yóò di adele fun alága àti ọ̀gá àgbà pátápátá náà.

Ìkìlọ̀ ẹ̀kun omi wáyé fún ìpínlẹ̀ méjìlá

Wo àlàyé bí Inec yóò se náwó nínú ìbò 2019

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBọla Tinubu: Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kò ní owó mi lọ́wọ́