2019 elections: Kíni ó ń fa èdèàìyedè lẹ́gbẹ́ APC ìpínlẹ̀ Eko

Gomina Ambọde nigba ti o lọ gba fọọmu iferongba han lati dije fun ipo gomina lolu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC nilu Abuja Image copyright @AkinwunmiAmbode
Àkọlé àwòrán Ni ọjọ aje ni gomina Ambọde gba fọọmu iferongba han lati dije fun ipo gomina lolu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC nilu Abuja

Gomina ìpínlẹ̀ Eko, Akinwumi Ambọde ni ko si ija kankan laarin oun ati aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Tinubu, bí àwọn kan sẹ n sọ.

Ọrọ naa jade lẹnu gomina ambọde nigba to n ba àwọn ọmọ ẹgbẹ osẹlu APC sọrọ lasiko eto idibo lati yan awsn aṣoju ti yoo ls fun idibo abẹle lati yan oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ naa, ati ipade gbogboogbo ẹgbẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọjọru ni Ambọde mu fọọmu to fifi erongba rẹ lati jẹ oludije ẹgbẹ naa ninu idibo sipo gomina l'ọdun 2019 han, lọ si olu ile ẹgbẹ All Progressives Congress to wa ni Abuja.

Eyi kiiṣe iyalẹnu, nitori anfaani wa fun ọpọlọpọ eniyan lati fi erongba wọn han bẹ ẹ ninu ẹgbẹ oṣelu. Ṣugbsn ohun to n kọ ọpọlọpọ lominuu ni fidio kan to ṣafihan awọn eniyan kan to sọ pe olori ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu, ''ti ta ami ororo le oludije tuntun naa l'ori.''

Iroyin yii lo tubọ mu ifunra dani pe o ṣeeṣe ki aarin gomina Ambode ati ẹni ti ọpọ mọ si baba isalẹ rẹ, Oloye Tinubu ko gun mọ bayii.

Lati ọdun 1999, saa meji-meji ni gbogbo awọn gomina to ti jẹ nipinlẹ Eko maa n lo lori oye

Kini ipilẹṣẹ ọrọ yii?

Fọran fidio kan to jade si ori ayelujara fi awọn alaga kansu kan han nibi ti wọn ti pade lati fi atilẹyin wọn han fun Jide Sanyaolu Sanwonolu ti wọn n ṣọọ kikankikan ninu fidio naa pe oun ni oloye Tinubu n fẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Eko.

Bi o tilẹ jẹ wi pe iroyin miran jade lati sọ pe gomina Ambode n gbeero lati gba ẹgbẹ oṣelu miran lọ bi APC ba kọọ, sugbọn ohun ti igun rẹ n sọ yanya ni pe ko si igba kan ti gomina ipinlẹ Eko naa sọ tabi pete-pero ati lọ si ẹgbẹ oṣelu miran.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ sí:

Ni ọjọ Aje ni gomina Ambọde gba fọọmu iferongba han lati dije fun ipo gomina lolu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC nilu Abuja.

Image copyright @AkinwunmiAmbode
Àkọlé àwòrán Gomina Ambode, Jide Sanwọnolu ati Ọbafẹmi Hamzat lo ti gbamu bayii laaring o#selu APC leko

Jide Sanyaolu Sanwonolu jẹ kọmiṣọna labẹ iṣejọba gomina ana nipinlẹ Eko Babatunde Faṣọla, ti Ambọde pẹlu si tun yan an gẹgẹ bii ọga agba ileeṣẹ to n mojuto ọrọ dukia nipinlẹ Eko, Lagos State Property Development Corporation (LSPDC) lọwọ yii.

Kini ero awọn onwoye lori ikanni ayelujara?

Image copyright @AkinwunmiAmbode
Àkọlé àwòrán Ohun to fidi rẹ mulẹ ni pe ohun to n fa eyi ko yẹ lẹyin bi wọn ṣe ni awọn eeyan kan dide lati ba gomina Ambode dije fun aṣia ẹgbẹ oṣelu

Ọrọ yii ti da ori ikanni ayelujara twitter ru bayii.

Bi awọn eeyan kan ṣe n foju aits wo igbesẹ ti wọn gbọ pe agba ọjẹ ẹgbẹ oṣelu naa, Bọla Tinubu gbe ni awọn kan n kan saara sii.

Ohun ti pupọ awọn ọdọ bii @iykimo, @bolanle_cole, @julietkego, @YarKafanchan ati bẹẹbẹẹ n sọ ni pe iyalẹnu ni bi awọn eeyan kan ni ipinlẹ Eko ti ṣe lee sa kuro lẹyin Ambọde lẹyin ti wọn ti fi ọdun mẹta yin in lawo 'fun iṣẹ takuntakun' ti o nṣe.

Amọṣa fun awọn eeyan bi @Kvngdvnni, @uzoakuchie, @chonsyy, @yinkanubi, ati omilẹgbẹ miran ko si ohun to bajẹ bi ẹgbẹ APC ba ri eniyan miran to mọọ ṣe ju gomina ambọde lọ.

Bẹẹni awọn miran woye pe eyi gan an ni yoo mu ki ere ije si ile ijọba ipinlẹ Eko ni Alausa o dun wo ni iran pẹlu bi nnkan ṣe n gbe'ra sọ bayii.

Kí lẹ mọ̀ nípa àwọn tó ń du àṣíá APC mọ́ gómínà Ekó lọ́wọ́?

Bi ọjọ ṣe n sun mọ'le fun idibo abẹle fun awọn oludije fun ipo gomina Ipinlẹ Eko labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ibeere ni awọn ara ilu n beere nipa awọn ti Gomina Akinwunmi Ambode yoo koju ninu idibo naa.

Ẹ o ranti wipe ẹgbẹ oṣelu naa ti pinu pe idibo abẹle ni wọn o fi yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa ni idibo gomina ti yoo waye ni 2019. Tẹlẹ ri, ẹni to ba wa lori aleefa ni wọn yoo gbe aṣia ẹgbẹ le lọwọ. Ṣugbọn ni bayii, awọn eekan ẹgbẹ ti n jade gba iwe mo-fẹ-dije.

Tani awọn ti yoo figa gbaga pẹlu Ambode naa?

Jide Sanwoolu

Oloselu yii jẹ kọmiṣọna ipo mẹta ọtọtọ ni Ipinlẹ Eko nigba kan ri. O ṣe kọmiṣọna fun karakata, kọmiṣọna fun iṣuna ati kọmiṣọna fun eto idagbasoke oṣiṣẹ. O jẹ oluranlọwọ pataki fun igbakeji gomina ni Ipinlẹ Eko nigba kan ri, Femi Pedro. Lẹyin naa ni olori ẹgbẹ APC, Bola Tinubu tun yan gẹgẹ bii oluranlọwọ pataki nigba to jẹ gomina.

Image copyright Facebook
Àkọlé àwòrán Jide Sanwoolu jẹ oluranlọwọ pataki fun Bola Tinubu nigba kan ri

Ki o to di pe Sanwoolu wọ agbo awọn oloṣelu, o ba awọn ile ifowopamọ oriṣiriṣi ṣiṣẹ. Oun ni adari ajọ Ipinlẹ Eko to n ri si akoso ile kikọ (LSDPC). O kẹkọ gboye meji ni fasiti Eko. Bẹẹ naa ni o lọ ile iwe imọ nipa owo ni orilẹede Amerika, Ilẹ Geesi ati ni Ilu Eko.

Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ iroyin lo ti n jade nipa awọn oludije bii Jide Sanwoolu

Obafemi Hamzat

Hamzat jẹ kọmiṣọna fun ọrọ sayẹnsi ati imọ ẹrọ lati ọdun 2005 titi di 2011 labẹ ijọba gomina ipinlẹ naa nigba kan ri, Bola Tinubu. Lẹyin naa nii gomina Ipinlẹ Eko nigba kan ri Babatunde Fashola yan gẹgẹ bii kọmiṣọna fun eto iṣẹ laarin ọdun 2011 si 2015. Ògbóǹtarìgì oloṣelu yii jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin ati kọmiṣọna fun irinna laarin ọdun 1979 si 1983. Oun tun ni igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu AD nigba kan ri.

Image copyright Facebook
Àkọlé àwòrán Onimọ ẹrọ ni Obafẹmi Hamzat

Hamzat to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelaadọta kẹkọ gboye imọ ẹrọ eto ọgbin ni fasiti Ibadan. O kẹkọọ siwaju si ni fasiti miran ni oke okun ki o to gboye ọmọwe ko to bẹrẹ si ṣiṣẹ ni orilẹede Amerika. Lẹyin naa lo pada wale lati ṣiṣẹ ni ileeṣẹ Oando.

Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán Obafẹmi Hamzat ti ni oun yoo gbe'na woju Ambode