PDP: Femi Otedola kò sọ pé òun yóò díje ní ìpínlẹ̀ Eko

Femi Otedola Image copyright @Femiotedola/Instagram
Àkọlé àwòrán Adari ipolongo fun ẹgbẹ oselu PDP, Kola Ologbondiyan ni Otedola ni di Ọjọ Kẹtadinlogun Osu yii lati sọ boya oun fẹ dije.

Ẹgbẹ oselu PDP ti tako iroyin to n kaakiri wipe Femi Otedola to ni ile isẹ epo bentirol Forte oil fẹ dije dupo gomina ni ipinlẹ Eko.

Gbajugbaja oniroyin Dele Momodu fi si oju opo ikansiraẹni Twitter rẹ wi pe ẹgbe oselu PDP ti yan Otedola gẹgẹbi ọkan lara awọn oludije si ipo gomina ni ipinlẹ Eko ni ọdun 2019.

Agbẹ̀nusọ fun ẹgbẹ oselu PDP, Kola Ologbondiyan to ba BBC Yoruba sọro ni Otedola ko i ti wa si olu ile isẹ ẹgbẹ oselu PDP ni ‘Wadata House’ ni Abuja lati wa fi ero rẹ han.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTẹniọla: Pè mí láago tí o bá mọ iyán gún pẹ̀lú ọbẹ̀ ilá tó dùn

Ologbọndiyan fikun wipe Femi Otedola ṣi ni di Ọjọ Kẹtadinlogun, Osu Kẹsan, ọdun yii lati ra fọọmu lati fi erongba rẹ han fun idije si ipo gomina ni ipinlẹ Eko.

Idibo gbogboogbo yoo waye ni orilẹede Naijiria ni Osu Keji, ọdun 2019.