Yemi Osinbajo: Ènìyàn 108 lò kú ní ìsẹ̀lẹ̀ omíyalé ní Kogi

Akute ni Ipinlẹ Ogun

Ijọba apaapọ orilẹede Naijiria ni wọn yoo se iranwọ fun awọn agbegbe ti omiyale ti ṣọsẹ ni ipinlẹ Kogi to wa ni apa aarin gbungun ariwa orilẹede Naijiria.

Igbakeji Aarẹ Naijiria, Yemi Osinbajo ti gomina ipinlẹ Kogi Yahaya Bello kọwọrin pẹlu lo sọ eyi lasiko to se abẹwo si ibudo awọn to lugbaji omiyale ni ile iwe Saint Luke's ni Koton-Karfe, ipinlẹ Kogi.

Osinbajo rọ awọn eniyan lati fọwọ sowọpọ pẹlu ara wọn lasiko ti wọn fi wa ni ibudo ogunlende naa, ki wọn le wa ni alaafia.

Àkọlé fídíò,

Adeleke fọhùn, 'èmi ni gómìnà tí wọ́n dìbò yàn'

Eniyan ọgọrun o le mẹjọ lo ba isẹlẹ naa lọ, ti ijọba ibilẹ aadọta si parẹ sinu ekun omi naa ni ipinlẹ Kogi.

Àgbàrá òjò lé ará ìlú kúrò nílé ní Ìpínlẹ̀ Ogun

Bakan náà, ojo to rọ ni Ipinlẹ Ogun ni ọjọ́ Iṣẹgun ti fa agbara ati omiyale to le ọgọrọ awọn ara ilu kuro nile ni Akute.

O pọ to bẹẹ ti wọn fi ni lati gbe ọkọ oju omi si aarin adugbo lati maa gbe awọn ara ilu kakakiri.

Bẹẹ ni awọn ti ko ri ọkọ oju omi sọ awọn ẹru inu ile wọn di ọkọ oju omi.

Tí ẹ bá rántí, aláṣẹ ìjọba lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti kọkọ sọ pé o lé ni ọgọ́rún kan ènìyàn ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn nípa àgbàrá omíyale àgbárá ya sọ́ọ̀bù tó ń ṣẹ̀lẹ̀ jákèjádò Nàìjíríà láàrín osẹ̀ méjì sẹ́yìn.

Àjọ àpapọ̀ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì NEMA sọ pé àgbàrá náà kò ṣẹ̀yìn òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá tó mú kí odò Niger àti Benue kún àkúnfàya.

Ìjọba ń rọ àwọn olugbé etí odò láti kúrò níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bi akọ̀ròyìn BBC, Ishaq Khalid ṣe sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ aburú yìí kárí Nàìjíríà ní sùgbọn ìpínlẹ̀ Niger ní àwọn ènìyàn ti kú jùlọ, ọ̀pọ̀ àwọn ìpínlẹ̀ tó wà ní ẹkùn aarin gbùngbùn Nàìjíríà lọ̀rọ̀ náà kàn.

Àkọlé fídíò,

Ìkọ BBC Yorùbá ṣe àbápade ọkùnrin tó ní òún le darí òjò síbi tó wù òun

Ọ̀gá àgbà àjọ náà, Mustapha Yunusa Maihaja sàlàyé fún BBC pé ènìyàn ogójì ló tí kú ni ìpínlẹ̀ náà. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tún kú ní àwọn ìpinlẹ̀ mọ́kànlá míràn.

Ọ̀pọ̀ àwọn ìlú ni ẹ̀kún omi ti dé ba pẹ̀lú, tó sì tí ṣí ọ̀pọ̀ nídìí kúrò ní ìbùgbé wọn pẹ̀lú gbogbo èrè oko wọn, bákan náà ní àjọ náà ni kí àwọn ènìyàn ṣì máa reti ẹkún omi ní Nàìjíríà ní àwọn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀

Awọn ìpínlẹ̀ méjìlá ti ọ̀rọ̀ náà kàn ní Niger, Kwara, Benue, Kogi, Adamawa, Taraba, Kebbi Bayelsa, Edo, Anambra, Rivers àti Delta.

Àkọlé fídíò,

Ọ̀rọ̀ Imam yìí ṣe kòńgẹ́ bó ti ń rí láàrin lọ́kọ láya