Linda Ikeji: Gbájugbaja àkọ̀ròyìn ẹ̀rọ alátagbà bímọ tuntun

Linda lori ibusun ile iwosan Image copyright @official Lindaikeji
Àkọlé àwòrán Linda Ikeji: Gbájugbaja àkọ̀ròyìn ẹ̀rọ alátagbà bímọ

Gbajúgbajà akọròyìn, àkọ̀wé, to tun jẹ onísowò nígbà kan rí, Linda Ikeji ti bímọ ọkunrin làntì-lanti.

Línda rìnrìn àjò lọ sí ìlú òyìnbó láti lọ bí ọmọ náà tó sì kédé rẹ lóri àtẹ̀jíṣẹ́ instagram rẹ̀ lówùrọ̀ òní.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'A máa ń bẹ́ orí ẹni tó bá gbé imọlẹ̀ ọdún ìjẹṣu tó bá ṣubú ni'

Linda kọ̀ láti jẹ̀ kí àwọn olólùfẹ́ rẹ mọ orúkọ ọmọ tuntun náà bó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní baby J láti osẹ̀ tó kọjá

Ikeji tó jẹ olówó jùlọ nínú àwọn àkọroyìn ori àtagbà tí ṣe ìkíni kààbọ fún ọmọ tuntun náà ní orílẹ-èdè Amẹrikà láti osẹ̀ tó kọjá nígbà ti wọn ń reti ọmọ jòjòló.

Psquare Peter Okoye, àbúro Linda, Laure Ikeji Kanu àti ọkọ rẹ̀ wà lára àwọn to wà níbi àpejẹ náà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀rọ̀ Imam yìí ṣe kòńgẹ́ bó ti ń rí láàrin lọ́kọ láya