Minisita ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ kò ní lé kópa nínú ìdìbò abẹ́lé APC nítorí ìwé ẹ̀rí àgùnbánirọ̀

Adebayo Shittu wà lára awọn to n díje fun ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán Adebayo Shittu wà lára awọn to fẹ́ díje fun ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ

Ẹgbẹ́ òsèlú All Progressives Congress, APC, ti kọ̀ láti buwọ́lu Mínísítà fún ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ , Adebayọ Shittu láti kópa nínú ètò ìdìbò abẹ́le ẹgbẹ́ nàá fún ipò gómínà.

Shittu tó n gbèrò láti di olùdíje ẹgbẹ́ nàá sípò gómínà ìpínlẹ̀ Ọyọ l'ọ́dún 2019 ní wọ́n yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò ní àwo ìdìbò abẹ́lé nàá nítorí pé kò ní ìwé ẹ̀rí ìsìnrú ìlú, NYSC.

Ìgbésẹ̀ ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá ẹgbẹ̀ nàá kò ṣẹ̀yìn àbájáde ìwádìí tí ìgbìmọ̀ tí wọ́n gbékalẹ̀ láti ṣàyẹ̀wò àwọn tó fẹ́ díje fún ipò gómìnà nínú ẹgbẹ́ nàá, bẹẹ, iwe èri agunbanirọ jẹ ọkan lara àwọn àmúyẹ lati lè dije fún ipo gomina ni Naijiria.

Báwo ni wàhálà ṣe bẹ̀rẹ̀ fún Shittu?

Lẹ́yìn awuyewuye to wáyé lori iwe ẹ̀rí agunbanirọ̀ minisita nigba kan ri fun ètò ìsuná, arabinrin Kemi Adeosun, minisita fun ọ̀rọ̀ ìbáraẹnisọ̀rọ̀, Adebayo Shittu ni wọn tun ti fẹ̀sùn kan pe ko ni iwe ẹ̀rí agunbanirọ.

Ile-isẹ̀ iroyin Premium Times lo fi ọ̀rọ̀ naa lẹ́de pe, Adebayo Shittu kùnà lati lọ fun ìsìnrú ilu ọlọ́dún kan to pọn dandan fun gbogbo awọn ti wọn ba pari ni ile ẹ̀kọ́ gíga, yala ni orilẹede Naijiria tabi loke òkun, lẹ́yìn to kẹ́kọ̀ọ́ gboye gẹ́gẹ́ bi agbẹjọ́rò ni Fásítì Ife ti a mọ̀ si Fasiti Obafemi Awolọwọ.

Gẹ́gẹ́ bi ile isẹ Premium Times ti sọ, ọ̀gbẹ́ni Shittu nígbà ti wọ́n kàn sii lati se ìwádìí ọ̀rs naa sọ pe, ko sí irọ́ ninu oun ti wọn sọ pe oun kọ̀ ni iwe ẹri agunbanirọ.

Shittu ni wọn ni o sàlàyé siwaju pe, òun ko nílò lati se ìsìnru ọlọdun kan ọun nitori pe, ni kété ti oun ti pari ni Fásitì ni oun ti wọnú òsèlú, èyí to túmọ̀ si pe, ipò òsèlu ti òún dìmú ti rọ́pò ìsìnrú ìlú to yẹ ki oun se.

Ni ọdun 1979 ni ọgbẹni Shittu di ọmọ ile ìgbìmọ̀ asòfin ní ìpínlẹ̀ Ọyọ, to si jẹ pe, ko pọn dandan lati ni iwe ẹ̀rí agunbanirọ lati di ipo naa mú.

Ki ni idi ti ìsìnrú ìlú se se pàtàkì?

Òfin to gbe àjọ NYSC kalẹ̀ lorilẹde Naijiria sọ pe o di dandan fun gbogbo ẹni to ba kàwé gboyè ni ile ẹ̀kọ́ giga, yálà lorilẹede Naijiria tabi loke òkun lati sinlẹ̀ baba wọn fun ọdun kan.

Ìsọ̀rí awọn eniyan mẹ́rin ni ofin yọ silẹ ninu ètò yii, àkọ́kọ́ ni awọn ti wọn ti le ni ọgbọ̀n ọdún ko to di pe wọn pari ni ile iwe gíga, èkeji ni awọn ti wọn ti sisẹ pẹlu ile isẹ ọlọ́pàá ati ológun fun ìwọ̀n osù mẹ́sàán, ikẹta ni awọn ti wọn n sisẹ níléesẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tabi awọn àjọ miiran to fara pẹ́ẹ.

Elẹ́ẹ̀kẹrin ni awọn ti wọn ba fi àmì ẹ̀yẹ ijọba àpapọ̀ da lọ́lá.