Joke Silva: Alágbàtọ́ ló gbà á nílé ọmọ aláìníyá, tó sì wò ó dàgbà

joke silva ati oko rẹ Image copyright joke/instagram
Àkọlé àwòrán Joke Silva: Modupe lọ́wọ́ àwọn algbatọ mi fún itóju wọn

Joke Silva jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn gbajúmọ òṣèré tíátà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, adarí eré àti onisòwò.

A bi i ni ọjọ kọkandínlọgbọ̀n oṣù kẹsàn-an ọdún 1961 ní ilú Eko. Adebimbola Silva to jẹ onisegun oyinbo ní iya rẹ, nígbà ti baba rẹ, E.A Silva jẹ agbẹjọrò, oun naa si ni Bọbajiro tilu Eko.

O lọ ilé ìwé girama Holy Child College nilu Eko, bákan náà ló ka èdè Oyinbo (English) ní fásítì Eko, o tún kàwé ni ibudo nipa ere tiata ti Webber Douglas Academy of Dramatic Art ní London.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌdunlade Adekọla gbóṣùbà fáwọn ọkùnrin tó ń ran ìyàwó wọn lọ́wọ́

Joke Silva bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ìtàgé rẹ̀ lati ọdún 1990, ọdún 1998 ló ṣe fíìmù tó gbée síta, to si gba àmì ẹyẹ oṣèrè tíàtà tó dara julọ.

Joke Silva ni àdari àkọkọ fún abúlé òṣèré (film Village) ti ile ẹkọ Fasiti Kwara (KWASU) dá sílẹ̀ lọdún 2014.

O gba ami ẹ̀yẹ OFR, to si ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré tíátà ní èdè oyinbo àti Yorùbá.

Image copyright @Jokeofficial
Àkọlé àwòrán Joke Silva: Modupe lọ́wọ́ àwọn algbatọ mi fún itóju wọn

Gẹgẹ bi a ti gbọ, awọn alagbatọ lo gba Joke Silva tọ ni ile ọmọ alainiya kan ni àdúgbò Yaba nilu Eko.

Nigba to n salaye bo se mọ pe awọn ti oun n pe ni obi oun kọ lo bi oun, Jọkẹ ni, "Mo jade pẹlu ibatan mi kan, la ba pade ẹbi wa miran ti wọn jẹ agbalagba, ibatan mi taa dijọ jade wa n fi mi han baba naa pe, emi ni ọmọ Dokita Silva. Para ni baba yii beere pe se Dokita Silva bimọ ni."

Jọkẹ ni lati igba ti isẹlẹ yii ti waye, ni oun ti n fura pe wọn gba oun wo ni bi o tilẹ jẹ pe mama oun ni isọkusọ ni baba naa sọ, nigba ti oun bii leere ọrọ̀ naa nigba tawọn de ile.

Image copyright Joke/instagram
Àkọlé àwòrán Joke Silva: Modupe lọ́wọ́ àwọn algbatọ mi fún itóju wọn

Amọ Jọkẹ salaye pe, akara tu sepo ni ọjọ kan ti oun n wa iwe asẹ irinna oun, taa mọ si Passport. O ni yara iya oun niwe naa wa, ti oun si ba awọn iwe ti wọn fi gba oun wo ninu iwe naa, lasiko ti iya oun ko si nile, eyi to fidi rẹ mulẹ pe tọkọ-taya Silva gba oun wo ni.

Jọkẹ Silva ni orukọ rẹ lasiko to ba n sere tiata, sugbọn aya Jacobs lo n jẹ ninu ile, nítoripe iyawo ni lọọdẹ Olu Jacobs, toun naa jẹ gbajugbaja oṣèré tíátà pẹ̀lú.

A gbọ pe wọn pàdé ara wọn lásìkò àyájọ ọdún ominira Naijiria lọdun 1981, ti Ọlọrun fi ọmọ méjì tawọn lọ́rẹ.

Image copyright Joke@official
Àkọlé àwòrán Joke Silva: Modupe lọ́wọ́ àwọn algbatọ mi fún itóju wọn

Biba yii ti Jọkẹ Silva tun le ọdun kan, a wa n gbadura pe yoo se ọpọlọpọ ọdun laye, ti a si maa ri pẹ pẹ pẹ loke eepẹ.