Ètò ẹ̀kọ́: Buhari dín owó fọ́ọ̀mù NECO, JAMB kù

Ọmọ ile iwe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọrọ eto ẹkọ

Ijọba apapọ ti kede ẹdinwo owo fọọmu idanwo aṣekagba nile iwe girama ti ajọ National Examination Council n ṣe ati idanwo ṣiṣe wọ ile iwe giga.

Minisita fun eto ẹkọ Ọgbẹni Adamu Adamu lo fọrọ naa lede lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ ijọba apapọ l'Ọjọru nilu Abuja.

Ẹdinwo naa ti Aarẹ Muhammadu ti buwọ lu yoo bẹrẹ ninu oṣu kinni ọdun 2019 gẹgẹ bi minisita eto ẹkọ ti sọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí

Owo ti wọn fi n gba fọọmu ati wọ ile iwe giga tẹlẹ JAMB yoo di ẹgbẹrun mẹta aabọ naira lati ẹgbẹrun marun un.

Oríṣun àwòrán, JAMB/FACEBOOK

Àkọlé àwòrán,

Ẹdinwo fọọmu idanwo

Idanwo NECO ti wọn n gba fọọmu rẹ tẹlẹ ni ẹgbẹrun mẹwaa aadọta din ni irinwo naira(11,350) yoo di ẹgbẹrun mẹwaa din aadọjọ naira(9,850).

Minisita ṣalaye pe idi ti ijọba fi gbe igbesẹ yii ni pe awọn ajọ idanwo ko wa lati maa pa wo wọle fun ijọba.

Pípọ́n ìwé ẹ̀rí lé ju ìmọ̀ lọ n kó bá ètò ẹ̀kọ́ l'órílẹ̀èdè Nàìjíríà.

L'ọ́jọ́bọ̀ tó kọjá ni ìjọba apapọ̀ àti àwọn gómìnà fẹnukò láti pé ìpè pájáwìrì lóri ètò ẹkọ́ l'áwọn ilé ìwé ìjọba jákèjádò gbogbo ìpínlẹ̀ ní Nàìjíríà.

Wọn ní bi ọ̀rọ̀ ètò ẹ̀kọ́ ṣe ń lọ kò bá ojú mú rárá, nítorí pé iná ètò ẹkọ́ ń jó àjórẹ̀yìn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Àwọn òbí kan tilẹ̀ tún maa n ra ìwé ẹ̀rí fún ọmọ wọn.

BBC Yorùbá ṣe ìwádìí lọ́wọ́ onímọ̀ nípa ètò ẹ̀kọ́ àti kíni ọ̀nà abáyọ láti le bori ìṣòrò eto ẹ̀kọ́ tó ti dàyà bolẹ̀.

Alhaji Rají Mohammed tó jẹ alákoso ètò ẹ̀kọ́ àti kọmisọnà fún ètò ẹkọ́ tẹ́lẹ̀rí ní ìpínlẹ̀ Kwara ṣe àtúpalẹ̀ àwọn ohun tó n kóbá ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí

Raji sọ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ orílẹ̀èdè yii dà bí ẹni pé a kò mọ ìtumọ̀ ẹ̀kọ́ ní Nàìjíríà. "Ó sì yẹ kí á ní àpérò lórí rẹ̀. A níló ìràpadà fún àwọn olùkọ́ wa."

Àwọn ohun tó wòye pé ó n ba ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà jẹ́ nìyíì.

''Àwọn ìṣòrò tó n ba ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà jẹ́''

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùkọ́ wa ní òde òní ní àwọn fúnra wọn kò mọ̀ nkan tí wọ́n n kọ́. Púpọ̀ wọn ni kò ṣe dáàda tó níléèwé girama tí wọ́n ti jáde. Àwọn ni wọ́n sì n gba iṣẹ́ olùkọ́ báyìí.

Àjọ tó n ṣe ìdánwò àṣewọlé sí àwọn iléèwé gíga ní Nàìjíríà nàá kò ṣe tó. Máàkì tí wọ́n maa n ló láti fi gba àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú àwọn iṣẹ́ bi i ìṣègùn òyìbó maa n pọ́, ṣùgbọ́n ti àwọn tó fẹ́ kọ̀ iṣẹ́ olùkọ́ maa n kéré.

Èyí túmọ̀ sí pé àwọn (Jamb) nàá mọ̀ pé àwọn tí kò ṣe daada ní iléèwé girama ló n fẹ́ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ olùkọ́.

Àwọn tí kò ríṣẹ́ ṣe ló n ṣiṣẹ́ olùkọ̀ l'óde òní. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní fásitì ní Nàìjíríà lásìkò yìí ló n gba iṣẹ́ olùkọ́ nítorí àìríkan ṣèkan. Wọ́n a sọ pé kí àwọn maa fi pawọ́dà títí tí àwọn yóò fi rí iṣẹ́ gidi ṣe.

Bákan nàá ni pé à n fún ìwé ẹ̀rí ní àpọ́nlé ju ìmọ̀ lọ l'órílẹ̀èdè Nàìjíríà. Púpọ̀ lára àwọ̀n akẹ́kọ̀ọ́ jáde níléèwé gíga ni kò lè fi ọwọ́ sọ̀yà lórí ìwé ẹ̀rí tí wọ́n gbà. Ẹlòmíì nínú wọn kò tilẹ̀ le kọ lẹ́tà tàbí kàwé dáàda.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní fásitì ní Nàìjíríà lásìkò yìí ló n gba iṣẹ́ olùkọ́ nítorí àìríkan ṣèkan.

Àwọn òbí kan tilẹ̀ tún maa n ra ìwé ẹ̀rí fún ọmọ wọn. Ó ṣeni láànú pé ìwé ẹ̀rí ti èèyàn ní là n wò, kíìṣe irú ìmọ̀ tí wọ́n ní.

Yíyí ètò ẹ̀kọ́ padà nàá n ṣe àkóbá fún ẹ̀ka ètò ẹ̀ka Nàìjíríà. Àwọn ìjọba tó n ṣe ìlànà ètò ẹ̀kọ́ (kòríkúlọ́ọ̀mù) kíì ṣe àwọn ohun tó yẹ́ tàbí pèsè àwọn ohun èlò. Wan kan n gbé òfin kalẹ̀ ni.

Àìsí àwọn iléèwé olùkọ́ni (Grade ) mọ́ bi i tàtijọ́ nàá n kó bá ètò ẹ̀kọ́ ló fi jẹ́ wí pé iléèwé NCE ni ọ̀pọ̀ ṣábà nlọ. Ọ̀pọ̀ àwọn NCE ọ̀hún ni kò sì yàtọ̀ sí iléèwé girama. Owó tí àwọn olùdásílẹ̀ wọn fẹ́ ẹ pa ní àfojúsùn wọn.

Titi oselu bọ ọrọ ẹkọ naa n ko ipalara ba eto ẹkọ. Fifi dandan le pe ọmọ ilu kan lo gbọdọ jẹ ọga ileewe ilu rẹ. Títí òṣèlú bọ ètò ẹ̀kọ́ lásìkò ìgbanisíṣẹ́ àti ìyànṣípò nàá n ṣe àkóbá fún ètò ẹ̀kọ́.

Ó wá sọ pé ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo ni pé kí ìjọba dẹ́kun irọ́ pípa fún aráàlú lórí ohun tí apá wọn ká láti ṣe. Wọn kò gbọdọ̀ sọ pé àwọn n pèsè ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, kì wan sì má pèsè ohun èlò ìkẹ́kọ̀ọ́. Kí wọ́n jẹ́ kí àwọn aráàlú mọ ohun tó yẹ́ fún wọn láti ṣe.

Bákan nàá ló rọ àwọn òbí láti mú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ọ̀kúnkúndùn, láà fi igbá kan bọ ọ̀kan nínú.