2019 Election: Ǹkan méje tó ò gbọdọ̀ se ní ọjọ́ ìdìbò

awon oludibo
Àkọlé àwòrán,

Mọ ohun ti o ko gbọdọ ṣe lasiko idibo Naijiria

Ajọ INEC ti sọ wi pe ijiya wa fun ẹnikẹni to ba tako ilana ati ofin to wa fun irọwọrọsẹ lasiko idibo lorilẹ-ede Naijiria.

Ikilọ yii wa saaju idibo gbogboogbo ti yoo waye lorilẹ-ede Naijiria ni osu keji si ikẹta, ọdun 2019.

Lori oju opo ikansiraẹni ti Ajọ INEC http://www.inecnigeria.org/ ni wọn ti fi lede iru awọn ohun aisedede ti ko gbọdọ waye ni ọjọ idibo ati ijiya ti yoo wa fun ẹni to ba tapa si awọn ofin naa.

Àkọlé fídíò,

Scrabble: Yorúbà Scrabble ni àkọ́kọ́ ní èdè abínibí nílẹ̀ Afrika

Nkan to o gbọdọ se ni ọjọ idibo gbogboogbo 2019

  • O ko gbọdọ ba ẹni to ba n dibo lọwọ sọrọ
  • O ko gbọdọ ra ibo tabi ta ibo
  • Ko si irina ọkọ ni ọjọ idibo
  • O ko gbọdọ polongo esi idibo ẹlẹjẹ
  • O ko gbọdọ mu kaadi idibo ti kii se tirẹ wa dibo
Àkọlé àwòrán,

Gẹ́gẹ́bí ìlànà Àjọ INEC, ìjẹ̀yà wà fún ẹnikẹ́ni tó bá wùwà tí kò tọ́ ní ọjọ́ ìdìbò gbogboògbò tí yóò wáyé lọ́dún 2019.

  • O ko gbọdọ fa ijangbọn tabi da agọ idibo ru.
  • O ko gbọdọ mu ohun ija oloro wa si ibi idibo
  • O ko gbọdọ wọ asọ, bata, fila tabi gele to fi mo ọkọ ayọkẹlẹ to se afihan ẹgbẹ oselu kankan.
  • O ko gbọdọ ji apoti idibo gbẹ ni ọjọ idibo.

Ajọ INEC fikun wi pe eto ijiya to to sisan owo toto miliọnu Naira tabi fi fi ẹwọn jura wa ninu ilana ijiya to wa fun ẹnikẹni to ba tapa si awọn ohun aigbọdọ mase ni ọjọ idibo wọn yii.

Àkọlé fídíò,

#NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí