Buhari @76: Goodluck Jonathan kí Ààrẹ Buhari kú ọjọ́ ìbí

Buhari ati Jonathan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọjọ́ Kẹtadinlogun, Osu Kejila ni Ààrẹ orílẹèdè Muhammadu Buhari yóò pé ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin.

Aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan ti ki Aarẹ Muhammadu Buhari ku ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.

Ninu atẹjade ti Jonathan fun ara rẹ buwọlu ni ilu Abuja,o dupẹ lọwọ Ọlọrun to fi ẹmi gigun da Aarẹ Buhari lọla ni ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin.

Jonathan ni Aarẹ Buhari ti se isẹ ribiribi pẹlu bi o se sin orilẹede Naijiria lati igba to ti wa ni ise ọmọogun Naijria , to tun jẹ gomina, minisita fun epo bẹntirọọlu, ọgaagun orilẹede Naijiria labẹ isejọba ologun ati nibayii to tun jẹ Aarẹ orilẹede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGbogbo ènìyàn ló wọ agbádá ikú, ẹni tó kàn lẹnìkan kò mọ̀

Aarẹ tẹlẹri naa to gboriyin fun Aarẹ Buhari naa, wa gbadura ẹmi gigun fun ati ilera lati lo igba aye rẹ ninu alaafia.