SSANU strike: ìyanṣẹ́lódì ọjọ́ mẹ́ta bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé

ui gate Image copyright @ui
Àkọlé àwòrán ko si si olukọ kankan ninu awọn yara ikẹkọ lati sisẹ ni ọgba fasiti Ibadan

Ọpọ eeyan lo ti n sọrọ lori ayelujara lori iyanṣẹlodi ti ẹgbẹ awọn olukọ agba ni awọn ile ẹkọ giga fasiti lorilẹ-ede Naijiria, SSANU gunle lọjọ Aje.

SSANU ni awọn n gun le iyansẹlodi naa nitori ijọba kọ lati bu ọla fun idajọ ile ẹjọ lori ọrọ awọn ile iwe alakọbẹrẹ ti fasiti ati bi ijọba se kuna lati san owo ajẹmọnu awọn osisẹ, lẹyin adehun ti wọn jọ buwọlu.

Ajọ naa ni ijọba apapọ ko lati da awọn olukọ ile iwe alakọbẹrẹ ti fasiti ti wọn da duro lẹnu ise pada si ipo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọrọ pọ ninu iwe kọbọ lori opo Twitter. Ẹnikan woye, o sọ pe ajọ ASUU lo kọkọ bẹrẹ iyanṣẹlodi ki ajọ NASS to bẹrẹ ti wọn. O ni awọn SSANU naa ti wa bẹrẹ ti wọn. O ni afaimọ ki iyanṣẹlodi ọhun ko maa di inu oṣu kọkanla to mbọ ko to pari.

Image copyright Wikipedia
Àkọlé àwòrán SSANU

Alao Abiodun tiẹ ni ajọ ASUU ati ASUP n yanṣẹlodi, bakan naa ajọ SSANU ti bẹrẹ ti wọn. O ni to ba ya, NASU naa yoo bẹrẹ tiẹ. Abiodun ni laisi aniani iṣoro nla wa pẹlu eto ẹkọ lorilẹ-ede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGbogbo ènìyàn ló wọ agbádá ikú, ẹni tó kàn lẹnìkan kò mọ̀

Ẹlomiran ni ijọba apapọ ko ni ṣe ohun ile ẹjọ paṣẹ rẹ. O ṣalaye pe Wọn ti gba beeli Sambo Dasuki ati olori ẹsin musulumi Shiite ṣugbọn wọn tun wa lẹwọn ni Kuje.

O ni to ba jẹ pe lorilẹede miran ni, ko yẹ ki Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ijọba orilẹede Naijiria rara lẹyin to ditẹ gbajọba lọdun 1983 eyi to mu ifasẹyin ba eto oṣelu Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlápinni: Kò sí ẹni to fẹ́ kọ́kọ́ kọ́ iṣẹ́ òṣèré bíi ti àtẹ̀yìnwá

Mohammed Ahmed Gorko ASUU ati ASUP wa lori iyanṣẹlodi, COESU sẹṣẹ fagile iyanṣẹlodi ti wọn. Ni bayii SSANU ti bẹrẹ ti wọn. O ni o ṣeni laanu pe ẹka eto ẹkọ ti doju keji lorilẹede Naijiria.

Ero awọn eeyan sọtọọtọ lori iyanṣẹlodi ti SSANU gunle lọjọ Aje lori opo facebook. Bi awọn kan ti n sọ pe awọn olosẹlu kan lo n lo ajọ awọn oṣiṣẹ ti wọn n daṣẹ silẹ lati ba ijọba to wa lode jẹ, bẹẹ ni awọn miran n sọ pe ijọba Buhari gan an ni ko ṣe ojuṣe rẹ.

Image copyright Facebook
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori iyansẹlodi SSANU

Yahaya Yakubu Muhammad ni asiko yii gan an ni ọpọlọpọ oṣiṣẹ fẹran lati maa gunle iyanṣẹlodi nitori idibo to mbọ.

Image copyright Facebook
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori iyansẹlodi SSANU