INEC: Yinka Ayefẹlẹ jẹ adari tootọ ni eto iroyin

YINKA AYEFELE Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti da gbajugbaja olorin, Yinka Ayefele lọla pẹlu oye asoju ajọ naa.

Ajọ INEC ti ni gbajugbaja olorin, Yinka Ayefele jẹ adari tootọ ni eto iroyin, iṣẹ ṣise ati idagbasoke awujọ lorilẹede Naijiria.

Yinka Ayefele ni alaga ati adari ile iṣẹ Iroyin Fresh FM ni ilu Ibadan.

Ajọ INEC sọ eyi lasiko ti wọn fi oye aṣoju ajọ naa da Yinka Ayefele lọla láti ẹnu igbakeji ẹka to n risi idanilẹkọ lori kaadi idibo, Abilekọ Lakunuya Dorothy Bello ni olu ilu Naijiria, Abuja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIlé orin wa tí Ajimobi tun kọ́ dára púpọ̀, ṣùgbọ́n a kò ní dẹ́kun òtítọ́

Pẹlu oye yii, ajọ naa ni ireti wi pe Ayefele yoo lo ipo rẹ lati mu ibugboro ba iroyin tootọ lasiko idibo gbogbogbo ti ọdun 2019.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGbogbo ènìyàn ló wọ agbádá ikú, ẹni tó kàn lẹnìkan kò mọ̀