Máákì fún ìbálópọ̀: Ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Akindele rẹ́wọ̀n ọdún méjì he

Richard Akindele Image copyright ICPC

Ile ẹjọ giga kan nilu Oṣogbo ti ran ọjọgbọn Richard Akindele ti ẹka iṣiro owo fasiti Obafemi Awolowo, Ile-Ife lọ ẹwọn ọdun meji lẹyin ti o ni oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Adajọ Maureen Onyekenu lo dajọ naa lẹyin ti Akindele yi ọrọ 'mi o jẹbi' rẹ si 'mo jẹ bi'.

Akindele wọ wahala ni oṣu kẹfa ọdun 2018 nigba ti akẹkọọbirin rẹ kan Monica Osagie fi ẹsun kan an pe o n foro ẹmi oun lori pe o fẹ ba oun lo pọ lori maaki.

Ọjọ Aje ni agbẹjọro ijọba, Shogunle Adenekan sọ nile ẹjọ wipe gbogbo awọn ti ọrọ naa kan ni o ti fẹnu ko lori ọrọ naa, eyi to faa ti Akindele ṣe ni oun jẹbi ni tootọ.

Igbọhunsilẹ kan lori ẹrọ ilewọ ti wọn fi ka ọrọ Akindele bi o ti ṣe n beere fun ibalopọ lọwọ ọmọbinrin naa, lo kọkọ ko ọjọgbọn naa si wahala.

Lẹyin to ni irọ ni wọn pa mọ oun ni fasiti OAU ṣe iwadii to fi han wipe ootọ ni pe ohun ọjọgbọn naa ni o wa lori igbohunsilẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFásitì OAU ní ohùn ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Akindele ni wọ́n ká sílẹ̀

Agbẹjọro Ọjọgbọn Akindele, Francis Omotosho ni ki adajọ fi oju aanu wo ọjọgbọn naa ṣugbọn adajọ kọ jalẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: